Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Poverty

12 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Òsì yóò sì wá sórí rẹ bí ìgárá ọlọ́ṣà àti àìní bí adigunjalè.

  2. Ọrọ̀ àwọn olódodo ni ìlú olódi wọn, ṣùgbọ́n òsì ni ìparun aláìní.

  3. Ó sàn kí ó má pọ̀, kí ìbẹ̀rù Olúwa sì wà ju ọrọ̀ púpọ̀ pẹ̀lú ìyọnu.

  4. Ó sàn kí ó kéré pẹ̀lú òdodo ju èrè púpọ̀ pẹ̀lú èrú lọ.

  5. Má ṣe fẹ́ràn oorun, àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ yóò di tálákà. Ma ṣe sùn ìwọ yóò sì ní oúnjẹ láti tún fi tọrọ.

  6. nítorí pé ọ̀mùtí àti ọ̀jẹun ni yóò di tálákà; ìmúni-tòògbé ní sì ń fi àkísà wọ ọkùnrin láṣọ.

  7. oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀, ìkáwọ́gbera díẹ̀ láti sinmi,

  8. òsì yóò sì dé bá ọ bí adigunjalè àti àìní bí olè.

  9. Ẹni tí ó bá ro ilẹ̀ rẹ̀ yóò ní oúnjẹ lọ́pọ̀lọ́pọ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ń lé ohun asán yóò kún fún òsì.

  10. Mú èké ṣíṣe àti irọ́ jìnnà sí mi; má ṣe fún mi ní òsì tàbí ọrọ̀, ṣùgbọ́n fún mi ní oúnjẹ òòjọ́ mi nìkan.

  11. Àìṣe bẹ́ẹ̀, mo lè ní àníjù kí n sì gbàgbé rẹ kí ń sì wí pé, ‘Ta ni Olúwa?’ Tàbí kí ń di òtòṣì kí ń sì jalè kí ń sì ṣe àìbọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run mi.

  12. Oúnjẹ ẹ̀kúnwọ́ kan pẹ̀lú ìdákẹ́ jẹ́ẹ́jẹ́ sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì pẹ̀lú wàhálà, àti gbígba ìyànjú àti lé afẹ́fẹ́ lọ.