Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Magistrates

22 ẹsẹ · 33 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Lẹ́yìn náà ni àwọn obìnrin alágbèrè méjì wá sọ́dọ̀ ọba, wọ́n sì dúró níwájú rẹ̀.

  2. Ọ̀kan nínú wọn sì wí pé, “Olúwa mi, èmi àti obìnrin yìí ń gbé nínú ilé kan. Èmi sì bí ọmọ ní ilé pẹ̀lú rẹ̀.

  3. Ní ọjọ́ kẹta lẹ́yìn ìgbà tí mo bímọ tan, obìnrin yìí sì bímọ pẹ̀lú. A sì nìkan dá wà; kò sí àlejò ní ilé bí kò ṣe àwa méjèèjì nìkan.

  4. “Ní òru, ọmọ obìnrin yìí kú nítorí tí ó sùn lé e.

  5. Nígbà náà ni ó sì dìde ní ọ̀gànjọ́, ó sì gbé ọmọ tèmi lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, nígbà tí èmi ìránṣẹ́ rẹ̀ ti sùn lọ. Ó sì tẹ́ ẹ sí àyà rẹ̀, ó sì tẹ́ òkú ọmọ tirẹ̀ sí àyà mi.

  6. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, mo sì dìde láti fi ọmú fún ọmọ mi: ó sì ti kú! Ṣùgbọ́n, nígbà tí mo sì wò ó fín ní òwúrọ̀, mo sì rí i pé kì í ṣe ọmọ mi tí mo bí.”

  7. Obìnrin kejì sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́! Èyí alààyè ni ọmọ mi, èyí òkú ni ọmọ tirẹ̀.” Èyí òkú ni tirẹ̀; èyí alààyè ni tèmi. Ṣùgbọ́n èyí àkọ́kọ́ tún wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́! Èyí òkú ni tìrẹ; èyí alààyè ni tèmi.” Báyìí ni wọ́n sì ń jiyàn níwájú ọba.

  8. Ọba sì wí pé, “Ẹni yìí wí pé, ‘Ọmọ mi ni ó wà láààyè, ọmọ tirẹ̀ ni ó kú,’ nígbà tí ẹni èkejì náà ń wí pé, ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́! Ọmọ tirẹ̀ ni ó kú, ọmọ tèmi ni ó wà láààyè.’ ”

  9. Nígbà náà ni ọba wí pé, “Ẹ mú idà fún mi wá.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì mú idà wá fún ọba.

  10. Ọba sì pàṣẹ pé, “Ẹ gé alààyè ọmọ sí méjì, kí ẹ sì mú ìdajì fún ọ̀kan, àti ìdajì fún èkejì.”

  11. Obìnrin tí ọmọ tirẹ̀ wà láààyè sì kún fún àánú fún ọmọ rẹ̀, ó sì wí fún ọba pé, “Jọ̀wọ́, olúwa mi, ẹ fún un ní alààyè ọmọ! Ẹ má ṣe pa á!” Ṣùgbọ́n obìnrin èkejì sì wí pé, “Kì yóò jẹ́ tèmi tàbí tìrẹ. Ẹ gé e sí méjì!”

  12. Nígbà náà ni ọba dáhùn, ó wí pé, “Ẹ fi alààyè ọmọ fún obìnrin àkọ́kọ́. Ẹ má ṣe pa á: òun ni ìyá rẹ̀.”

  13. Nígbà tí gbogbo Israẹli gbọ́ ìdájọ́ tí ọba ṣe, wọ́n sì bẹ̀rù níwájú ọba, nítorí wọ́n ti rí í pé ó ní ọgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run láti ṣe ìdájọ́.

  14. Nígbà tí Esra ń gbàdúrà tí ó sì ń jẹ́wọ́, ti ó ń sọkún ti ó sì ń gbárayílẹ̀ níwájú ilé Ọlọ́run, ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ Israẹli ọkùnrin, obìnrin àti àwọn ọmọdé pagbo yí i ká. Àwọn náà ń sọkún kíkorò.

  15. Nígbà náà ni Ṣekaniah ọmọ Jehieli, ọ̀kan lára ìran Elamu, sọ fún Esra pé, “Àwa ti jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run wa nípa fífẹ́ àwọn obìnrin àjèjì láàrín àwọn ènìyàn tí ó wà yí wa ká. Ṣùgbọ́n síbẹ̀ náà, ìrètí sì wà fún Israẹli

  16. Nísìnsinyìí, ẹ jẹ́ kí a dá májẹ̀mú níwájú Ọlọ́run wa láti lé àwọn obìnrin yìí àti àwọn ọmọ wọn lọ. Gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ràn Esra olúwa mi àti ti àwọn tí ó bẹ̀rù àṣẹ Olúwa Ọlọ́run wa. Ẹ jẹ́ kí a ṣe gẹ́gẹ́ bí òfin.

  17. Dìde, nítorí, ọ̀rọ̀ tìrẹ ni èyí. Gbogbo wà yóò wá pẹ̀lú rẹ, mú ọkàn le kí o sì ṣe é.”

  18. Nígbà náà ni Esra dìde, ó sì fi àwọn aṣíwájú àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi àti gbogbo Israẹli sí abẹ́ ìbúra, láti ṣe ohun tí wọ́n dá lábàá. Wọ́n sì búra.

  19. Nígbà náà ni Esra padà sẹ́yìn kúrò níwájú ilé Ọlọ́run, ó sì lọ sí iyàrá Jehohanani ọmọ Eliaṣibu. Nígbà tí ó wà níbẹ̀, kò jẹ oúnjẹ bẹ́ẹ̀ ni kò sì mu omi, nítorí ó sì ń káàánú fún àìṣòótọ́ àwọn ìgbèkùn.

  20. Ìkéde kan jáde lọ jákèjádò Juda àti Jerusalẹmu fún gbogbo àwọn ìgbèkùn láti péjọ sí Jerusalẹmu.

  21. Ẹnikẹ́ni tí ó ba kọ̀ láti jáde wá láàrín ọjọ́ mẹ́ta yóò pàdánù ohun ìní rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìpinnu àwọn ìjòyè àti àwọn àgbàgbà, àti pé a ó lé òun fúnra rẹ̀ jáde kúrò láàrín ìpéjọpọ̀ àwọn ìgbèkùn.

  22. Láàrín ọjọ́ mẹ́ta náà, gbogbo àwọn ọkùnrin Juda àti Benjamini tí péjọ sí Jerusalẹmu. Ní ogúnjọ́ oṣù kẹsànán, gbogbo àwọn ènìyàn jókòó sí ìta gbangba iwájú ilé Ọlọ́run, wọ́n wà nínú ìbànújẹ́ ńlá nítorí ọ̀ràn yìí, àti nítorí òjò púpọ̀ tó tì rọ̀.