Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Leprosy

61 ẹsẹ · 50 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò bí ó bá jinlẹ̀ ju awọ ara lọ tí irun ibẹ̀ sì pọ́n fẹ́ẹ́rẹ́ tí kò sì kún; kí àlùfáà pe ẹni náà ní aláìmọ́; làpálàpá ni èyí. Ààrùn tí ń ràn ká orí tàbí àgbọ̀n ni.

  2. Ṣùgbọ́n bí àlùfáà bá yẹ egbò yìí wò tí kò sì jinlẹ̀ ju àwọ̀ ara lọ tí kò sì sí irun dúdú kan níbẹ̀. Kí àlùfáà fi ẹni náà pamọ́ fún ọjọ́ méje.

  3. Ní ọjọ́ keje kí àlùfáà yẹ ojú ibẹ̀ wò, bí làpálàpá náà kò bá ràn mọ́ tí kò sì sí irun pípọ́n fẹ́ẹ́rẹ́ nínú rẹ̀ tí kò sì jinlẹ̀ ju àwọ̀ ara lọ.

  4. Kí a fá gbogbo irun rẹ̀ ṣùgbọ́n kí ó dá ojú àpá náà sí, kí àlùfáà sì tún fi pamọ́ fún ọjọ́ méje mìíràn.

  5. Kí àlùfáà yẹ làpálàpá náà wò, ní ọjọ́ keje bí kò bá ràn ká gbogbo àwọ̀ ara, tí kò sì jinlẹ̀ ju inú àwọ̀ ara lọ. Kí àlùfáà pè é ní mímọ́, kí ó fọ aṣọ rẹ̀, òun yóò sì mọ́.

  6. Ṣùgbọ́n bí làpálàpá náà bá ràn ká àwọ̀ ara rẹ̀ lẹ́yìn tí a ti fihàn pé ó ti mọ́.

  7. Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò bí làpálàpá náà bá ràn ká àwọ̀ ara; kí àlùfáà má ṣe yẹ irun pupa fẹ́ẹ́rẹ́ wò mọ́. Ẹni náà ti di aláìmọ́.

  8. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìdájọ́ àlùfáà pé ẹni náà kò mọ́, tí ojú làpálàpá náà kò bá yípadà, tí irun dúdú si ti hù jáde lójú rẹ̀. Làpálàpá náà ti san. Òun sì ti di mímọ́. Kí àlùfáà fi í hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ti di mímọ́.

  9. “Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan bá ní ojú àpá funfun lára àwọ̀ ara rẹ̀.

  10. Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò, bí ojú àpá náà bá funfun ààrùn ara tí kò léwu ni èyí tí ó farahàn lára rẹ̀, ẹni náà mọ́.

  11. “Bí irun ẹnìkan bá rẹ̀ dànù tí ó sì párí. Ẹni náà mọ́.

  12. Bí irun ẹnìkan bá rẹ̀ dànù níwájú orí tí ó sì párí níwájú orí. Ẹni náà mọ́.

  13. Ṣùgbọ́n bí ó bá ní egbò pupa fẹ́ẹ́rẹ́ ní ibi orí rẹ̀ tí ó pá, tàbí níwájú orí rẹ̀, ààrùn tí ń ràn ká iwájú orí tàbí ibi orí ni èyí.

  14. Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò bí egbò tó wù níwájú orí rẹ̀ tàbí tí orí rẹ̀ bá pupa díẹ̀ tí ó dàbí ààrùn ara tí ń rànkálẹ̀.

  15. Aláàrùn ni ọkùnrin náà, kò sì mọ́, kí àlùfáà pe ẹni náà ní aláìmọ́ torí egbò tí ó wà ní orí rẹ̀.

  16. “Bí ààrùn yìí bá tún farahàn lẹ́yìn tí a ti yọ àwọn òkúta wọ̀nyí tí a sì ti ha ilé náà ti a sì tún rẹ́ ẹ.

  17. Àlùfáà yóò tún lọ yẹ̀ ẹ́ wò bí ààrùn náà bá tún gbilẹ̀ sí i nínú ilé náà: ẹ̀tẹ̀ apanirun ni èyí, ilé náà jẹ́ aláìmọ́.

  18. Wíwó ni kí a wó o, gbogbo òkúta ilé náà, àwọn igi àti gbogbo ohun tí a fi rẹ́ ẹ ni kí a kó jáde nínú ìlú sí ibi tí a kà sí àìmọ́.

  19. Láti sọ ilé yìí di mímọ́. Àlùfáà yóò mú ẹyẹ méjì àti igi kedari òdòdó àti hísópù.

  20. Yóò sì pa ọ̀kan nínú àwọn ẹyẹ náà sórí omi tí ó mọ́ nínú ìkòkò amọ̀.

  21. Kí ó ri igi kedari, hísópù, òdòdó àti ààyè ẹyẹ náà bọ inú ẹ̀jẹ̀ òkú ẹyẹ àti omi tí ó mọ́ náà kí ó fi wọ́n ilẹ̀ náà lẹ́ẹ̀méje.

  22. Yóò fi ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ náà, omi tí ó mọ́, ààyè ẹyẹ, igi kedari, hísópù àti òdòdó sọ ilé náà di mímọ́.

  23. Kí àlùfáà ju ààyè ẹyẹ náà sílẹ̀ lẹ́yìn ìlú. Báyìí ni yóò ṣe ètùtù fún ilé náà. Ilé náà yóò sì mọ́.”

  24. “Sọ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ kí wọ́n fi ọ̀wọ̀ fún ọrẹ mímọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli yà sọ́tọ̀ fún mi, kí wọ́n má ba à ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́. Èmi ni Olúwa.

  25. “Sọ fún wọn pé, ‘Fún àwọn ìran tí ń bọ̀. Bí ẹnikẹ́ni nínú àwọn ọmọ yín tí kò mọ́ bá wá sí ibi ọrẹ mímọ́ tí àwọn ara Israẹli ti yà sọ́tọ̀ fún Olúwa, kí ẹ yọ ẹni náà kúrò nínú iṣẹ́ àlùfáà ní iwájú mi. Èmi ni Olúwa.