Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Judge

91 ẹsẹ · 6 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ṣa àwọn tí ó kún ojú òsùwọ̀n nínú gbogbo àwọn ènìyàn, àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run, ti wọ́n jẹ́ olóòtítọ́, tí wọ́n kórìíra ìrẹ́jẹ; yàn wọ́n ṣe olórí, lórí ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún, ọgọ́rùn-ún ọgọ́rùn-ún, àádọ́ta-dọ́ta àti mẹ́wàá mẹ́wàá.

  2. Jẹ́ kí wọn ó máa ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn ni gbogbo ìgbà, ṣùgbọ́n jẹ́ kí wọn mú ẹjọ́ tí ó bá nira fún wọn láti dá tọ̀ ọ́ wá; kí wọn kí ó máa dá ẹjọ́ kéékèèké. Èyí ni yóò mú iṣẹ́ rẹ rọrùn, wọn yóò sì máa ràn ọ́ lọ́wọ́ lórí ìdájọ́ ṣíṣe.

  3. Báwo ni èmi nìkan ṣe lè máa ru àjàgà àti ìṣòro yín àti èdè-àìyedè yín?

  4. Ẹ yan àwọn ọlọ́gbọ́n, olóye àti àwọn ẹni àpọ́nlé, láti inú ẹ̀yà yín kọ̀ọ̀kan, èmi yóò sì fi wọ́n ṣe olórí yín.”

  5. Ẹ̀yin sì dá mi lóhùn wí pé, “Ohun tí ìwọ ti gbèrò láti ṣe nì dára.”

  6. Bẹ́ẹ̀ ni mo yan olórí àwọn ẹ̀yà yín, àwọn ọlọ́gbọ́n ọkùnrin, ẹni àpọ́nlé, mo sì fi jẹ olórí yín, olórí ẹgbẹẹ̀rún, olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún, olórí àràádọ́ta, àti olórí mẹ́wàá mẹ́wàá gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀yà yín.

  7. Mo sì kìlọ̀ fún àwọn onídàájọ́ yín nígbà náà pé, ẹ gbọ́ èdè-àìyedè tí ó wà láàrín àwọn ènìyàn an yín kí ẹ sì ṣe ìdájọ́ òdodo, bóyá ẹjọ́ tí ó ṣẹlẹ̀ láàrín Israẹli sí Israẹli ni tàbí láàrín Israẹli kan sí àlejò.

  8. Ẹ má sì ṣe ojúsàájú ní ìdájọ́. Ẹ ṣe ìdájọ́ ẹni ńlá àti kékeré bákan náà. Ẹ má ṣe bẹ̀rù ẹnikẹ́ni torí pé ti Ọlọ́run ni ìdájọ́. Ẹjọ́ tí ó bá le jù fún un yín ni kí ẹ mú wá fún mi. Èmi yóò sì gbọ́ ọ.

  9. Ẹ yan àwọn adájọ́ àti àwọn olóyè fún ẹ̀yà a yín kọ̀ọ̀kan, ní gbogbo ìlú tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò fún un yín, wọ́n sì gbọdọ̀ máa fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn.

  10. Ìwọ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ po, ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúsàájú ènìyàn. Ìwọ kò gbọdọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ nítorí pé àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ń fọ́ ojú ọlọ́gbọ́n, ó sì ń ba ọ̀rọ̀ olódodo jẹ́.

  11. Ẹ tẹ̀lé ìdájọ́ òtítọ́ àní ìdájọ́ òtítọ́ nìkan, kí ẹ bá à lè gbé kí ẹ sì gba ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín ń fún un yín.

  12. Bí ẹjọ́ bá wá sí ilé ẹjọ́ èyí tí ó nira jù láti dá, yálà ìtàjẹ̀ sílẹ̀ ni, ọ̀ràn dídá tàbí ìkanni-lábùkù, ẹ mú wọn lọ sí ibi tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò yàn.

  13. Ẹ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn àlùfáà tí í ṣe Lefi, àní sí ọ̀dọ̀ adájọ́ tí ó wà fún ìgbẹ́jọ́ ní ìgbà náà. Ẹ béèrè lọ́wọ́ wọn, wọn yóò sì ṣe ìdájọ́.

  14. Kí ìwọ kí ó sì ṣe bí ọ̀rọ̀ ìdájọ́, ti àwọn ará ibi tí Olúwa yóò yàn náà yóò fihàn ọ, kí ìwọ kí ó sì máa kíyèsí àti máa ṣe gẹ́gẹ́ bi gbogbo èyí tí wọn kọ́ ọ.

  15. Ẹ ṣe bí òfin tí wọ́n kọ́ ọ yín, àti ìpinnu tí wọ́n fún un yín. Ẹ má ṣe yípadà sọ́tùn tàbí sósì, kúrò nínú ohun tí wọ́n sọ fún un yín.

  16. Tí alárankàn ẹlẹ́rìí èké bá dúró láti fi ẹ̀sùn ẹ̀ṣẹ̀ kan ọkùnrin kan,

  17. àwọn méjèèjì tí àríyànjiyàn wà láàrín wọn gbọdọ̀ dúró níwájú Olúwa níwájú àwọn àlùfáà àti àwọn adájọ́ tí ó wà ní ibi iṣẹ́ ní ìgbà náà.

  18. Àwọn adájọ́ gbọdọ̀ ṣe ìwádìí fínní fínní bí ẹ̀rí bá sì jẹ́ irọ́, tí ó fi ẹ̀rí èké sun arákùnrin rẹ̀,

  19. nígbà náà ni kí ó ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ó ṣe fẹ́ ṣe sí arákùnrin rẹ̀. O ní láti wẹ búburú kúrò láàrín rẹ.

  20. Nígbà tí àwọn ènìyàn méjì bá ń jà, kí wọn kó ẹjọ́ lọ sí ilé ìdájọ́, kí àwọn onídàájọ́ dá ẹjọ́ náà, kí wọn dá àre fún aláre àti ẹ̀bi fún ẹlẹ́bi.

  21. Bí ó bá tọ́ láti na ẹlẹ́bi, kí onídàájọ́ dá a dọ̀bálẹ̀ kí a sì nà án ní ojú u rẹ̀ ní iye pàṣán tí ó tọ́ sí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sẹ̀.

  22. Ṣùgbọ́n kò gbọdọ̀ fún un ju ogójì pàṣán lọ. Bí ó bá nà án ju bẹ́ẹ̀ lọ, arákùnrin rẹ̀ yóò di ẹni ìrẹ̀sílẹ̀ ní ojú rẹ̀.

  23. Lẹ́yìn náà ni àwọn obìnrin alágbèrè méjì wá sọ́dọ̀ ọba, wọ́n sì dúró níwájú rẹ̀.

  24. Ọ̀kan nínú wọn sì wí pé, “Olúwa mi, èmi àti obìnrin yìí ń gbé nínú ilé kan. Èmi sì bí ọmọ ní ilé pẹ̀lú rẹ̀.

  25. Ní ọjọ́ kẹta lẹ́yìn ìgbà tí mo bímọ tan, obìnrin yìí sì bímọ pẹ̀lú. A sì nìkan dá wà; kò sí àlejò ní ilé bí kò ṣe àwa méjèèjì nìkan.