Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Idol: Manufacture of

8 ẹsẹ · 5 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Manufacture of

  1. Ní ti ère, oníṣọ̀nà ni ó dà á, ti alágbẹ̀dẹ wúrà sì fi wúrà bò ó tí a sì ṣe ẹ̀wọ̀n ọ̀nà sílífà fún un.

  2. Ọkùnrin kan tí ó tálákà jù kí ó lè mú irú ọrẹ bẹ́ẹ̀ wá, wá igi tí kò le è rà. Ó wá oníṣọ̀nà tí ó láti ṣe àgbékalẹ̀ ère tí kì yóò le è ṣubú.

  3. Gbogbo àwọn tí ń gbẹ́ ère jásí asán, àti àwọn ohun tí wọn ń kó pamọ́ kò jámọ́ nǹkan kan. Àwọn tí yóò sọ̀rọ̀ fún wọn fọ́ lójú; wọ́n jẹ́ aláìmọ̀kan sí ìtìjú ara wọn.

  4. Ta ni ó mọ òrìṣà kan tí ó sì ya ère, tí kò lè mú èrè kankan wá fún un?

  5. Òun àti nǹkan rẹ̀ wọ̀nyí ni a ó dójútì; àwọn oníṣọ̀nà kò yàtọ̀, ènìyàn ni wọ́n. Jẹ́ kí gbogbo wọn gbárajọ kí wọ́n sì fi ìdúró wọn hàn; gbogbo wọn ni a ó mú bọ́ sínú ìpayà àti àbùkù.

  6. Alágbẹ̀dẹ mú ohun èlò, ó fi ń ṣiṣẹ́ nínú èédú; ó fi òòlù ya ère kan, ó ṣe é pẹ̀lú agbára apá rẹ̀, ebi ń pa á, àárẹ̀ sì mú un; kò mu omi rárá, ìrẹ̀wẹ̀sì dé bá a.

  7. Nítorí ọkùnrin kan tí a ń pè ní Demetriusi, alágbẹ̀dẹ fàdákà, tí o máa ń fi fàdákà ṣe ilé òrìṣà fún Artemisi, ó mú ère tí kò mọ níwọ̀n wá fún àwọn oníṣọ̀nà.

  8. Nígbà tí ó pè wọ́n jọ, àti irú àwọn oníṣẹ́-ọnà bẹ́ẹ̀, ó wí pé, “Alàgbà, ẹ̀yin mọ̀ pé nípa iṣẹ́ ọnà yìí ni àwa fi ní ọrọ̀ wa.