Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Idol

13 ẹsẹ · 5 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Elijah sì wí fún àwọn wòlíì Baali wí pé, “Ẹ yan ẹgbọrọ akọ màlúù kan fún ara yín, kí ẹ sì tètè kọ́ ṣe é, nítorí ẹ̀yin pọ̀. Ẹ ké pe orúkọ àwọn ọlọ́run yín, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe fi iná sí i.”

  2. Nígbà náà ni wọ́n sì mú ẹgbọrọ akọ màlúù náà, tí a ti fi fún wọn, wọ́n sì ṣe é. Nígbà náà ni wọ́n sì ké pe orúkọ Baali láti òwúrọ̀ títí di ọ̀sán gangan wí pé, “Baali! Dá wa lóhùn!” Wọ́n sì ń kégbe. Ṣùgbọ́n kò sí ìdáhùn; kò sí ẹnìkan tí ó sì dáhùn. Wọ́n sì jó yí pẹpẹ náà ká, èyí tí wọ́n tẹ́.

  3. Ní ọ̀sán gangan, Elijah bẹ̀rẹ̀ sí ń fi wọ́n ṣe ẹlẹ́yà ó sì wí pé, “Ẹ kígbe lóhùn rara Ọlọ́run sá à ni òun! Bóyá ó ń ṣe àṣàrò, tàbí kò ráyè, tàbí ó re àjò. Bóyá ó sùn, ó yẹ kí a jí i.”

  4. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì kígbe lóhùn rara, wọ́n sì fi ọ̀bẹ àti ọ̀kọ̀ ya ara wọn gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn, títí tí ẹ̀jẹ̀ fi tú jáde ní ara wọn.

  5. Nígbà tí ọjọ́ yẹ àtàrí, wọ́n sì ń fi òmùgọ̀ sọtẹ́lẹ̀ títí di àkókò ìrúbọ àṣálẹ́, ṣùgbọ́n kò sí ohùn, kò sì ṣí ìdáhùn, kò sì ṣí ẹni tí ó kà á sí.

  6. Ní ti ère, oníṣọ̀nà ni ó dà á, ti alágbẹ̀dẹ wúrà sì fi wúrà bò ó tí a sì ṣe ẹ̀wọ̀n ọ̀nà sílífà fún un.

  7. Ọkùnrin kan tí ó tálákà jù kí ó lè mú irú ọrẹ bẹ́ẹ̀ wá, wá igi tí kò le è rà. Ó wá oníṣọ̀nà tí ó láti ṣe àgbékalẹ̀ ère tí kì yóò le è ṣubú.

  8. Gbogbo àwọn tí ń gbẹ́ ère jásí asán, àti àwọn ohun tí wọn ń kó pamọ́ kò jámọ́ nǹkan kan. Àwọn tí yóò sọ̀rọ̀ fún wọn fọ́ lójú; wọ́n jẹ́ aláìmọ̀kan sí ìtìjú ara wọn.

  9. Ta ni ó mọ òrìṣà kan tí ó sì ya ère, tí kò lè mú èrè kankan wá fún un?

  10. Òun àti nǹkan rẹ̀ wọ̀nyí ni a ó dójútì; àwọn oníṣọ̀nà kò yàtọ̀, ènìyàn ni wọ́n. Jẹ́ kí gbogbo wọn gbárajọ kí wọ́n sì fi ìdúró wọn hàn; gbogbo wọn ni a ó mú bọ́ sínú ìpayà àti àbùkù.

  11. Alágbẹ̀dẹ mú ohun èlò, ó fi ń ṣiṣẹ́ nínú èédú; ó fi òòlù ya ère kan, ó ṣe é pẹ̀lú agbára apá rẹ̀, ebi ń pa á, àárẹ̀ sì mú un; kò mu omi rárá, ìrẹ̀wẹ̀sì dé bá a.

  12. Nítorí ọkùnrin kan tí a ń pè ní Demetriusi, alágbẹ̀dẹ fàdákà, tí o máa ń fi fàdákà ṣe ilé òrìṣà fún Artemisi, ó mú ère tí kò mọ níwọ̀n wá fún àwọn oníṣọ̀nà.

  13. Nígbà tí ó pè wọ́n jọ, àti irú àwọn oníṣẹ́-ọnà bẹ́ẹ̀, ó wí pé, “Alàgbà, ẹ̀yin mọ̀ pé nípa iṣẹ́ ọnà yìí ni àwa fi ní ọrọ̀ wa.