Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Heart

30 ẹsẹ · 2 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ṣùgbọ́n láti ọkàn ni èrò búburú ti wá, bí ìpànìyàn, panṣágà, àgbèrè, olè jíjà, irọ́ àti ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́.

  2. Àwọn tí a dárúkọ wọ̀nyí ni ó ń sọ ènìyàn di aláìmọ́. Ṣùgbọ́n láti jẹun láì wẹ ọwọ́, kò lè sọ ènìyàn di aláìmọ́.”

  3. Nítorí nígbà tí àwọn aláìkọlà, tí kò ní òfin, bá ṣe ohun tí ó wà nínú òfin nípa ìwà ẹ̀dá, àwọn wọ̀nyí, jẹ́ òfin fún ara wọn bí wọn kò tilẹ̀ ní òfin.

  4. Àwọn ẹni tí ó fihàn pé, a kọ̀wé iṣẹ́ òfin sí wọn lọ́kàn, tí ẹ̀rí ọkàn wọn pẹ̀lú sì tún ń jẹ́ wọn lẹ́rìí, àti pé, èrò ọkàn wọn tí ó jẹ́ ọ̀nà ìfinisùn, sì ń gbè wọ́n lẹ́yìn ní ìsinsin yìí.

  5. Èyí yóò farahàn ní ọjọ́ náà nígbà tí Ọlọ́run yóò tipasẹ̀ Jesu Kristi ṣe ìdájọ́ àwọn àṣírí ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìyìnrere mi.