Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Heart: Known to God

17 ẹsẹ · 2 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Known to God

  1. Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu. Olúwa, ìwọ tí wádìí mi, ìwọ sì ti mọ̀ mí.

  2. Ìwọ mọ̀ ìjókòó mi àti ìdìde mi, ìwọ mọ̀ èrò mi ní ọ̀nà jíjìn réré.

  3. Ìwọ yí ipa ọ̀nà mi ká àti ìdùbúlẹ̀ mi, gbogbo ọ̀nà mi sì di mí mọ̀ fún ọ.

  4. Nítorí tí kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ahọ́n mi, kíyèsi i, Olúwa, ìwọ mọ̀ ọ́n pátápátá.

  5. Ìwọ sé mi mọ́ lẹ́yìn àti níwájú, ìwọ sì fi ọwọ́ rẹ lé mi.

  6. Irú ìmọ̀ yìí jẹ ohun ìyanu fún mi jù; ó ga, èmi kò le mọ̀ ọ́n.

  7. Níbo ní èmi yóò gbé lọ kúrò ni ọwọ́ ẹ̀mí rẹ? Tàbí níbo ni èmi yóò sáré kúrò níwájú rẹ?

  8. Bí èmi bá gòkè lọ sí ọ̀run, ìwọ wà níbẹ̀; bí èmí ba sì tẹ́ ẹní mi ní ipò òkú, kíyèsi i, ìwọ wà níbẹ̀ pẹ̀lú.

  9. Èmi ìbá mú ìyẹ́ apá òwúrọ̀, kí èmi sì lọ jókòó ní ìhà òpin Òkun,

  10. àní, níbẹ̀ náà ni ọwọ́ rẹ̀ yóò fà mí ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì dì mímú.

  11. Bí mo bá wí pé, “Ǹjẹ́ kí òkùnkùn kí ó bò mí mọ́lẹ̀; kí ìmọ́lẹ̀ kí ó di òru yí mi ká.”

  12. Nítòótọ́ òkùnkùn kì í ṣú lọ́dọ̀ rẹ; ṣùgbọ́n òru tan ìmọ́lẹ̀ bí ọ̀sán; àti òkùnkùn àti ọ̀sán, méjèèjì bákan náà ní fún ọ.

  13. Èmi yóò fún wọn ní ọ̀kankan; èmi yóò sì fi ẹ̀mí tuntun sínú wọn, Èmi yóò mú ọkàn òkúta kúrò lára wọn, èmi yóò sì fún wọn ní ọkàn tó rọ̀ bí ara ẹran.

  14. Kí wọn le tẹ̀lé àṣẹ mi, kí wọn sì le pa òfin mi mọ́. Wọ́n yóò jẹ́ ènìyàn mi, Èmi náà yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn.

  15. Ṣùgbọ́n fún àwọn tí wọ́n ń fi gbogbo ọkàn wọn sin àwọn àwòrán ìríra àti àwọn òrìṣà, Èmi yóò mú ẹ̀san ohun tí wọ́n ṣe wá sí orí wọn bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Olódùmarè wí.”

  16. Èmi yóò wọ́n omi tó mọ́ sí yín lára ẹ̀yin yóò sì mọ́; Èmi yóò sì fọ̀ yín mọ́ kúrò nínú gbogbo ìwà èérí yin gbogbo àti kúrò nínú gbogbo òrìṣà yin.

  17. Èmi yóò fún yín ni ọkàn tuntun, èmi yóò sì fi ẹ̀mí tuntun sínú yín; Èmi yóò sì mú ọkàn òkúta kúrò nínú yín, èmi yóò sì fi ọkàn ẹran fún yín.