Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Egypt: Infatuation of its princes
Àwọn ẹsẹ nípa Infatuation of its princes
Àwọn oníṣẹ́ Ṣoani ti di aláìgbọ́n, àwọn ọlọ́gbọ́n olùdámọ̀ràn Farao ń mú ìmọ̀ràn àìgbọ́n wá. Báwo ló ṣe lè sọ fún Farao pé, “Mo jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àwọn ọba àtijọ́.”
Níbo ni àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn rẹ wà báyìí? Jẹ́ kí wọn fihàn ọ́ kí wọn sì sọ ọ́ di mí mọ̀ ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti pinnu lórí Ejibiti.
Àwọn ọmọ-aládé Ṣoani ti di aṣiwèrè, a ti tan àwọn ọmọ-aládé Memfisi jẹ; àwọn òkúta igun ilé tí í ṣe ti ẹ̀yà rẹ ti ṣi Ejibiti lọ́nà.
Olúwa ti da ẹ̀mí òòyì sínú wọn; wọ́n mú Ejibiti ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nínú ohun gbogbo tí ó ń ṣe, gẹ́gẹ́ bí ọ̀mùtí ti í ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nínú èébì rẹ̀.