Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Egypt: Destruction of its cities

5 ẹsẹ · 105 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Destruction of its cities

  1. Èmi yóò sì mú kí Paturosi di ahoro, èmi yóò fi iná sí Ṣoani, èmi yóò sì fi ìyà jẹ Tebesi.

  2. Èmi yóò tú ìbínú mi jáde sórí Pelusiumu ìlú odi Ejibiti èmi yóò sì ké àkójọpọ̀ Tebesi kúrò.

  3. Èmi yóò ti iná bọ Ejibiti Pelusiumu yóò japoró ní ìrora. Ìjì líle yóò jà ní Tebesi Memfisi yóò wà ìpọ́njú ní ìgbà gbogbo.

  4. Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ní Heliopolisi àti Bubasiti yóò ti ipa idà ṣubú wọn yóò sì kó àwọn ìlú wọn ní ìgbèkùn.

  5. Ojú ọjọ́ yóò ṣókùnkùn ní Tafanesi nígbà tí mo bá já àjàgà Ejibiti kúrò; níbẹ̀ agbára iyì rẹ̀ yóò dópin wọn yóò fi ìkùùkuu bò ó àwọn abúlé rẹ ní wọn yóò lọ sí ìgbèkùn.