Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Consolation Under Affliction: Promised

7 ẹsẹ · 22 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Promised

  1. Dájúdájú, Olúwa yóò tu Sioni nínú yóò sì bojú àánú wo gbogbo ahoro rẹ̀; Òun yóò sọ gbogbo aṣálẹ̀ rẹ̀ di Edeni, àti aṣálẹ̀ rẹ̀ yóò rí bí ọgbà Olúwa. Ayọ̀ àti inú dídùn ni a ó rí nínú rẹ̀, ọpẹ́ àti ariwo orín kíkọ.

  2. “Èmi, àní Èmi, èmi ni ẹni tí ó tù ọ́ nínú. Ta ni ọ́ tí o fi ń bẹ̀rù ènìyàn ẹlẹ́ran ara, àti ọmọ ènìyàn, tí ó jẹ́ koríko lásán,

  3. Gẹ́gẹ́ bí ìyá ti í tu ọmọ rẹ̀ nínú, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò tù yín nínú a ó sì tù yín nínú lórí Jerusalẹmu.”

  4. Síbẹ̀, yóò ṣẹ́kù àwọn díẹ̀, àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin tí a ó kó jáde nínú rẹ̀. Wọn yóò wá bá yin, ẹ̀yin yóò rí ìwà àti ìṣe wọn, nígbà náà ni ẹ̀yin yóò rí ìtùnú nípa àjálù tí mo mú wá sórí Jerusalẹmu—àní gbogbo àjálù ní mo ti mú wá sórí rẹ̀.

  5. Nígbà tí ẹ̀yin bá rí ìwà àti ìṣe wọn, a ó tù yín nínú, nítorí pé ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi kò ṣe nǹkan kan láìnídìí, ni Olúwa Olódùmarè wí.”

  6. “Nítorí náà, èmi yóò tàn án, Èmi ó sì mú u lọ sí ilẹ̀ aṣálẹ̀, Èmi ó fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bá a sọ̀rọ̀

  7. “Máa ké síbẹ̀ pé, báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘A o máa fi ìre kún ìlú ńlá mi síbẹ̀; Olúwa yóò sì máa tu Sioni nínú síbẹ̀, yóò sì yan Jerusalẹmu síbẹ̀.’ ”