Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Boasting

66 ẹsẹ · 3 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run tí yàn àwọn òmùgọ̀ ayé láti fi dààmú àwọn ọlọ́gbọ́n; Ọlọ́run sì ti yàn àwọn ohun aláìlera ayé láti fi dààmú àwọn ohun tí ó ni agbára.

  2. Àti àwọn ohun tí ayé tí kò ní ìyìn, àti àwọn ohun tí a kẹ́gàn, ni Ọlọ́run sì ti yàn, àní àwọn ohun tí kò sí, láti sọ àwọn ohun tí ó wà di asán.

  3. Nítorí kí ó má ba à sí ẹnìkan tí yóò ṣògo níwájú rẹ̀.

  4. Nítorí rẹ̀ ni ẹ̀yin ṣe wà nínú Kristi Jesu ẹni ti ó jásí ọgbọ́n fún wa láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run—èyí ń ni, òdodo, ìwà mímọ́ àti ìràpadà wa.

  5. Nítorí náà, bí a ti kọ ọ́ pé, “Ẹni ti ó bá ń ṣògo kí ó máa ṣògo nínú Olúwa.”

  6. Ẹ kíyèsi i pé, mo ti fi ara mi àti Apollo ṣe àpẹẹrẹ nǹkan tí mo wí, pé kí ẹ̀yin lè ti ipa wa kọ́ láti máa ṣe ohun tí a ti kọ̀wé kọjá. “Kí ẹnikẹ́ni nínú yín má ṣe tìtorí ẹnìkan gbéraga sí ẹnìkejì.”

  7. Nítorí ta ni ó mú ọ yàtọ̀ sí àwọn ẹlòmíràn? Kí ni ìwọ ni tí ìwọ kò rí gbà? Tí ìwọ ba sì gbà á, èétiṣe tí ìwọ fi ń halẹ̀ bí ẹni pé ìwọ kò gba á?

  8. Nítorí pé àwa kò dáṣà láti ka ara wa mọ́, tàbí láti fi ara wa wé àwọn mìíràn nínú wọn tí ń yin ara wọn; ṣùgbọ́n àwọn fúnra wọn jẹ́ aláìlóye bí wọn ti ń fi ara wọn díwọ̀n ara wọ́n, tí wọ́n sì ń fi ara wọn wé ara wọn.

  9. Ṣùgbọ́n àwa kò ṣògo rékọjá ààlà wa, ṣùgbọ́n nípa ààlà ìwọ̀n tí Ọlọ́run ti pín fún wa, èyí tí ó mú kí ó ṣe é ṣe láti dé ọ̀dọ̀ yín.

  10. Nítorí àwa kò nawọ́ wa rékọjá rárá, bí ẹni pé àwa kò dé ọ̀dọ̀ yín: nítorí àwa tilẹ̀ dé ọ̀dọ̀ yín pẹ̀lú nínú ìyìnrere Kristi.

  11. Àwa kò ṣògo rékọjá ààlà wa, èyí nì, lórí iṣẹ́ ẹlòmíràn, ṣùgbọ́n àwa ní ìrètí pé, bí ìgbàgbọ́ yín ti ń dàgbà sí i, gẹ́gẹ́ bí ààlà wa, àwa ó dí gbígbéga lọ́dọ̀ yín sí i lọ́pọ̀lọ́pọ̀.

  12. Kí a bá à lè wàásù ìyìnrere ní àwọn ìlú tí ń bẹ níwájú yín, kí a má sì ṣògo nínú ààlà ẹlòmíràn nípa ohun tí ó wà ní àrọ́wọ́tó.

  13. “Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ẹni tí ó bá ń ṣògo, kí ó máa ṣògo nínú Olúwa.”

  14. Nítorí oore-ọ̀fẹ́ ní a fi gbà yín là nípa ìgbàgbọ́. Èyí kì í ṣe nípa agbára ẹ̀yin fúnra yín: ẹ̀bùn Ọlọ́run ni,

  15. kì í ṣe nípa àwọn iṣẹ́, kí ẹnikẹ́ni má ba à ṣògo.

  16. Nítorí àwa ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ tí a ti dá nínú Kristi Jesu fún àwọn iṣẹ́ rere, èyí tí Ọlọ́run ti pèsè tẹ́lẹ̀, fún wa láti ṣe.