Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Beasts: Horse

7 ẹsẹ · 90 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Horse

  1. “Ìwọ ni ó fi agbára fún ẹṣin bí, tàbí ṣé ìwọ ni ó fi gọ̀gọ̀ wọ ọrùn rẹ̀ ní aṣọ?

  2. Ìwọ le mú fò sókè bí ẹlẹ́ǹgà? Ògo èémí imú rẹ ní ẹ̀rù ńlá.

  3. Ó fi ẹsẹ̀ halẹ̀ nínú àfonífojì, ó sì yọ̀ nínú agbára rẹ̀; ó lọ jáde láti pàdé àwọn ìhámọ́ra ogun.

  4. Ó fi ojú kékeré wo ẹ̀rù, àyà kò sì fò ó; bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í padà sẹ́yìn kúrò lọ́wọ́ idà.

  5. Lọ́dọ̀ rẹ ni apó-ọfà ń mì pẹkẹpẹkẹ, àti ọ̀kọ̀ dídán àti àpáta.

  6. Ó fi kíkorò ojú àti ìbínú ńlá gbé ilé mi, bẹ́ẹ̀ ni òun kò sì gbà á gbọ́ pé, ìró ìpè ni.

  7. Ó wí nígbà ìpè pé, Háà! Háà! Ó sì gbóhùn ogun lókèèrè réré, igbe àwọn balógun àti ìhó ayọ̀ ogun wọn.