Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Absalom: David's mourning for

9 ẹsẹ · 10 abala

Àwọn ẹsẹ nípa David's mourning for

  1. Ọba sì kẹ́dùn púpọ̀ ó sì gòkè lọ, sí yàrá tí ó wà lórí òkè ibodè, ó sì sọkún; báyìí ni ó sì ń wí bí ó ti ń lọ, “Ọmọ mi Absalomu! Ọmọ mi, ọmọ mí Absalomu! Á à! Ìbá ṣe pé èmi ni ó kú ní ipò rẹ̀! Absalomu ọmọ mi, ọmọ mi!”

  2. A sì rò fún Joabu pe, “Wò ó, ọba ń sọkún, ó sì ń gbààwẹ̀ fún Absalomu.”

  3. Ìṣẹ́gun ọjọ́ náà sì di àwẹ̀ fún gbogbo àwọn ènìyàn náà, nítorí àwọn ènìyàn náà gbọ́ ní ọjọ́ náà bí inú ọba ti bàjẹ́ nítorí ọmọ rẹ̀.

  4. Àwọn ènìyàn náà sì yọ́ lọ sí ìlú ní ọjọ́ náà gẹ́gẹ́ bí àwọn bí ènìyàn tí a dójútì ṣe máa ń yọ́ lọ nígbà tí wọ́n bá sá lójú ìjà.

  5. Ọba sì bo ojú rẹ̀, ọba sì kígbe ní ohùn rara pé, “Á à! Ọmọ mi Absalomu! Absalomu ọmọ mi, ọmọ mi!”

  6. Joabu sì wọ inú ilé tọ ọba lọ, ó sì wí pé, “Ìwọ dójúti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ lónìí, àwọn tí ó gba ẹ̀mí rẹ̀ là lónìí, àti ẹ̀mí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àti ti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀, àti àwọn aya rẹ̀, àti ẹ̀mí àwọn obìnrin rẹ.

  7. Nítorí pé ìwọ fẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ, ìwọ sì kórìíra àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Nítorí tí ìwọ wí lónìí pé, Ìwọ kò náání àwọn ọmọ ọba tàbí àwọn ìránṣẹ́; èmi sì rí lónìí pé, ìbá ṣe pé Absalomu wà láààyè, kí gbogbo wa sì kú lónìí, ǹjẹ́ ìbá dùn mọ́ ọ gidigidi.

  8. Sì dìde nísinsin yìí, lọ, kí o sì sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ, nítorí pé èmi fi Olúwa búra, bí ìwọ kò bá lọ, ẹnìkan kì yóò bá ọ dúró ni alẹ́ yìí, èyí ni yóò sì burú fún ọ ju gbogbo ibi tí ojú rẹ ti ń rí láti ìgbà èwe rẹ wá títí ó fi di ìsinsin yìí.”

  9. Ọba sì dìde, ó sì jókòó ní ẹnu-ọ̀nà, wọ́n sì wí fún gbogbo àwọn ènìyàn náà pé, “Wò ó, ọba jókòó ní ẹnu-ọ̀nà.” Gbogbo ènìyàn sì wá sí iwájú ọba. Nítorí pé, Israẹli ti sá, olúkúlùkù sí àgọ́ rẹ̀.