Skip to content

Manasseh

24 ẹsẹ · 4 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Manasses

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Manasseh

  1. Hesekiah sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀: Manase ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

  2. Manase jẹ́ ẹni ọdún méjìlá nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ìjọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún márùndínlọ́gọ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Hẹfisiba.

  3. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kò tẹ́tí. Manase tàn wọ́n síwájú, bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n lè ṣe búburú ju gbogbo orílẹ̀-èdè tí Olúwa tí parun níwájú àwọn ọmọ Israẹli lọ.

  4. “Manase ọba Juda ti ṣe ẹ̀ṣẹ̀ ohun ìríra. Ó ti ṣe ohun búburú jùlọ ju àwọn ará Amori lọ ẹni tí ó ti wà ṣáájú rẹ̀ tí ó sì ti ṣáájú Juda sínú ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú àwọn ère rẹ̀.

  5. Pẹ̀lúpẹ̀lú, Manase pẹ̀lú ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ púpọ̀ tí ó kún Jerusalẹmu láti ìkangun dé ìkangun ní ẹ̀gbẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti mú Juda ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni, kí wọ́n lè ṣe ohun búburú ní ojú Olúwa.

  6. Ní ti iṣẹ́ ìyókù ti ìjọba Manase, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, àti fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀, ṣé wọ́n kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn àwọn ọba Juda?

  7. Manase sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ wọ́n sì sin ín nínú ọgbà ààfin rẹ̀, ọgbà Ussa. Amoni ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

  8. Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa àti gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ Manase ti ṣe.

  9. Ó wó o palẹ̀ pẹpẹ tí àwọn ọba Juda ti wọ́n gbé dúró ní orí òrùlé lẹ́bàá yàrá òkè ti Ahasi pẹ̀lú àwọn pẹpẹ tí Manase ti kọ́ nínú ilé ẹjọ́ méjèèjì sí ilé Olúwa. Ó ṣí wọn kúrò níbẹ̀, ó fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́. Ó sì da ekuru wọn sínú àfonífojì Kidironi.

  10. Bí ó ti wù kí ó rí Olúwa kò yípadà kúrò nínú ìmúná ìbínú ńlá rẹ̀ tí ó jó sí Juda, nítorí gbogbo èyí tí Manase ti ṣe láti mú un bínú.

  11. Nítòótọ́ eléyìí ṣẹlẹ̀ sí Juda gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa, láti mú wọn kúrò níwájú rẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Manase àti gbogbo nǹkan tí ó ṣe.

  12. Ahasi ọmọ rẹ̀, Hesekiah ọmọ rẹ̀, Manase ọmọ rẹ̀,

  13. Hesekiah sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. A sì sin ín sórí òkè níbi tí àwọn ibojì àwọn àtẹ̀lé Dafidi wà. Gbogbo Juda àti àwọn ènìyàn Jerusalẹmu ni ó bu ọlá fún un nígbà tí ó kú. Manase ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

  14. Manase jẹ́ ọmọ ọdún méjìlá nígbà tí ó di ọba. Ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún márùndínlọ́gọ́ta.

  15. Ṣùgbọ́n Manase mú kí Juda àti àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu yapa, àti láti ṣe búburú ju àwọn orílẹ̀-èdè lọ, àwọn tí Olúwa ti parun níwájú àwọn ọmọ Israẹli.

  16. Olúwa bá Manase sọ̀rọ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò kọbi ara sí i.

  17. Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa mú àwọn alákòóso ọmọ-ogun ọba Asiria láti dojúkọ wọ́n, tí ó mú Manase nígbèkùn, ó fi ìwọ̀ mú un ní imú rẹ̀, ó dè é pẹ̀lú ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ idẹ ó sì mú un lọ sí Babeli.

  18. Nígbà tí ó sì gbàdúrà sí i, inú Olúwa dùn sí àdúrà rẹ̀, ó sì tẹ́tí sí ẹ̀bẹ̀ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni ó mú un padà wá sí Jerusalẹmu àti sí ìjọba rẹ̀. Nígbà náà Manase mọ̀ wí pé Olúwa ni Ọlọ́run.

  19. Àwọn iṣẹ́ yòókù ti ìjọba Manase pẹ̀lú àdúrà rẹ̀ sí Ọlọ́run rẹ̀ àti àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn aríran sọ sí i ní orúkọ Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, wà nínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli.

  20. Manase sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín sínú ààfin rẹ̀. Amoni ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

  21. Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ Manase ti ṣe. Amoni rú ẹbọ sí gbogbo àwọn òrìṣà tí Manase baba rẹ̀ ti ṣe, ó sì sìn wọ́n.

  22. Ṣùgbọ́n kì í ṣe bí i baba rẹ̀ Manase. Kò rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Olúwa: ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ Amoni sì ń pọ̀ sì í.

  23. N ó sọ wọ́n di ẹni ìkórìíra níwájú gbogbo ìjọba ayé torí ohun tí Manase ọmọ Hesekiah ọba Juda ṣe ní Jerusalẹmu.

  24. Hesekiah ni baba Manase; Manase ni baba Amoni; Amoni ni baba Josiah;