Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Èmi yóò fún yín ni ọkàn tuntun, èmi yóò sì fi ẹ̀mí tuntun sínú yín; Èmi yóò sì mú ọkàn òkúta kúrò nínú yín, èmi yóò sì fi ọkàn ẹran fún yín.

  2. Èmi yóò fi ẹ̀mí mi sínú yín, èmi yóò sì mú ki ẹ tẹ̀lé àṣẹ mi, kí ẹ sì fiyèsí àti pa òfin mi mọ́.

  3. Ẹ̀yin yóò sì máa gbé ilẹ̀ náà tí mo ti fi fún àwọn baba ńlá yín; ẹ̀yin yóò sì jẹ́ ènìyàn mi èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín.

  4. Èmi yóò sì gbà yín kúrò nínú gbogbo ìwà àìmọ́ yín. Èmi yóò pèsè ọkà, èmi yóò sì mú kí ó pọ̀ yanturu, èmi kì yóò sì mú ìyàn wá sí orí yín.

  5. Èmi yóò sọ èso àwọn igi yín àti ohun ọ̀gbìn oko yín di púpọ̀, nítorí kí ẹ̀yin kí ó má ṣe jìyà ìdójútì mọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè náà nítorí ìyàn.

  6. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ń kò ṣe nǹkan wọ̀nyí nítorí yín, ni Olúwa Olódùmarè wí. Jẹ kí ojú kí ó tì yín, kí ẹ sì gba ẹ̀tẹ́ nítorí ìwà yín ẹ̀yin ilé Israẹli!

  7. “ ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Ní ọjọ́ tí mo wẹ̀ yín kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín gbogbo, èmi yóò ṣe àtúnṣe àwọn ìlú yín, wọn yóò sì ṣe àtúnkọ́ ìwólulẹ̀.

  8. Nígbà náà àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà ní àyíká yín tí ó kù yóò mọ̀ pé, Èmi Olúwa ti tún àwọn ohun tí ó bàjẹ́ kọ́, mo sì ti tún ohun tí ó di ìṣòfo gbìn. Èmi Olúwa ti sọ̀rọ̀, èmi yóò sì ṣe e?’

  9. “Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè sọ: Lẹ́ẹ̀kan sí i èmi yóò yí sí ilé Israẹli, èmi yóò sì ṣe èyí fún wọn. Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn yín pọ̀ lọ́pọ̀lọ́pọ̀ bí àgùntàn,

  10. kí ó pọ̀ lọ́pọ̀lọ́pọ̀ bí ọ̀wọ́ ẹran fún ìrúbọ ní Jerusalẹmu ní àsìkò àjọ̀dún tí a yàn. Ìlú ti a parun yóò wá kún fún agbo àwọn ènìyàn. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.”

  11. Ọwọ́ Olúwa wà lára mi, ó sì mú mi jáde pẹ̀lú ẹ̀mí Olúwa, ó mú kí ń wà ní àárín àfonífojì; ti o kún fún àwọn egungun.

  12. Olúwa sì bi mí léèrè, “Ọmọ ènìyàn, ǹjẹ́ àwọn egungun wọ̀nyí lè yípadà di àwọn ènìyàn bí?” Èmi sì wí pé, “Ìwọ Olúwa Olódùmarè, ìwọ nìkan ni o lè dáhùn sí ìbéèrè yìí.”

  13. Nígbà náà ni ó wí fún mi pé, “Sọtẹ́lẹ̀ sí àwọn egungun kí ó sì sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin egungun gbígbẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa!

  14. Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí fún àwọn egungun wọ̀nyí. Èmi yóò mú kí èémí wọ inú yín ẹ̀yin yóò sì wá di ààyè.

  15. Èmi yóò so iṣan ara mọ́ ọn yín, Èmi yóò sì mú kí ẹran-ara wá sí ara yín, Èmi yóò sì fi awọ ara bò yín, Èmi yóò sì fi èémí sínú yín, ẹ̀yin yóò sì wà ní ààyè. Nígbà náà ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’ ”

  16. Lẹ́yìn náà ni ó sọ fún mi pé, “Sọtẹ́lẹ̀ sí èémí; sọtẹ́lẹ̀, ọmọ ènìyàn, kí ó sì sọ fún un pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: wá láti atẹ́gùn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, ìwọ èémí, kí ó sì mí èémí sínú àwọn tí a pa wọ̀nyí, kí wọn kí ó lè wà ní ààyè.’ ”

  17. Nítorí náà, mo sọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe pa á láṣẹ fún mi, èémí sì wọ inú wọn; wọ́n di alààyè, wọ́n sì dìde dúró lórí ẹsẹ̀ wọn—pẹ̀lú ìhámọ́ra tí ó pọ̀.

  18. Lẹ́yìn náà ó sọ fún mi: “Ọmọ ènìyàn, àwọn egungun wọ̀nyí ni gbogbo ìdílé Israẹli. Wọ́n sọ wí pé, ‘Egungun wa ti gbẹ ìrètí wa sì ti lọ; a ti gé wa kúrò.’

  19. Nítorí náà sọtẹ́lẹ̀, kí o sì sọ fun wọn pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè sọ: Ẹ̀yin ènìyàn mi, Èmi yóò ṣí àwọn ibojì yín, èmi yóò sì mú yín wá si ilẹ̀ Israẹli.

  20. Ẹ̀yin o sì mọ̀ èmi ni Olúwa, nígbà tí èmi bá ti ṣí ibojì yín, ẹ̀yin ènìyàn mi, ti èmi bá si mú un yín dìde kúrò nínú ibojì yín.

  21. Èmi yóò fi èémí mi sínú yín, ẹ̀yin yóò sì yè, èmi yóò sì mú kí ẹ fi lélẹ̀ ní ilẹ̀ ẹ̀yin tìkára yín. Nígbà náà ẹ̀yin yóò mọ̀ pé Olúwa ti sọ̀rọ̀, èmi sì ti ṣe ni Olúwa wí.’ ”

  22. Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mi wá:

  23. Sọ fún wọn pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Èmi yóò gba igi Josẹfu—èyí tí ó wà ní ọwọ́ Efraimu—àti ti ẹ̀yà Israẹli tí ó parapọ̀ mọ́ ọn, kí ó sì só papọ̀ mọ́ igi Juda, láti sọ wọ́n di igi kan ṣoṣo, wọn yóò sì di ọ̀kan ní ọwọ́ mi.’

  24. kí ó sì sọ fún wọn pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Èmi yóò mú Israẹli jáde kúrò ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti lọ. Èmi yóò ṣà wọ́n jọ pọ̀ láti gbogbo agbègbè, èmi yóò sì mú wọn padà sí ilẹ̀ ara wọn.

  25. Èmi yóò ṣe wọ́n ní orílẹ̀-èdè kan ní ilẹ̀ náà, ní orí òkè Israẹli, ọba kan ni yóò wà lórí gbogbo wọn, wọn kì yóò sì jẹ́ orílẹ̀-èdè méjì mọ́, tàbí kí a pín wọn sí ìjọba méjì.