Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Tribes of Israel: Descended from Jacob's sons
Àwọn ẹsẹ nípa Descended from Jacob's sons
Nígbà tí Israẹli sì ń gbé ní ibẹ̀, Reubeni wọlé tọ Biliha, àlè baba rẹ̀ lọ, ó sì bá a lòpọ̀, Israẹli sì gbọ́ ọ̀rọ̀ náà. Jakọbu sì bí ọmọkùnrin méjìlá.
Àwọn ọmọ Lea, Reubeni tí í ṣe àkọ́bí Jakọbu, Simeoni, Lefi, Juda, Isakari àti Sebuluni.
Àwọn ọmọ Rakeli: Josẹfu àti Benjamini.
Àwọn ọmọ Biliha ìránṣẹ́bìnrin Rakeli: Dani àti Naftali.
Àwọn ọmọ Silipa ìránṣẹ́bìnrin Lea: Gadi àti Aṣeri. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ tí Jakọbu bí ní Padani-Aramu.