Sefaniah 2:1-7
1
Ẹ kó ara yín jọ pọ̀, àní ẹ kó ra yín jọ pọ̀ orílẹ̀-èdè tí kò ní ìtìjú,
2
kí a tó pa àṣẹ náà, kí ọjọ́ náà tó kọjá bí ìyàngbò ọkà, kí gbígbóná ìbínú Olúwa tó dé bá a yín, kí ọjọ́ ìbínú Olúwa kí ó tó dé bá a yín.
3
Ẹ wá Olúwa, gbogbo ẹ̀yin onírẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ náà, ẹ̀yin tí ń ṣe ohun tí ó bá pàṣẹ. Ẹ wá òdodo, ẹ wá ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú, bóyá á ó pa yín mọ́ ní ọjọ́ ìbínú Olúwa.
4
Nítorí pé, a ó kọ Gasa sílẹ̀, Aṣkeloni yóò sì dahoro. Ní ọ̀sán gangan ni a ó lé Aṣdodu jáde, a ó sì fa Ekroni tu kúrò.
5
Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ń gbé etí Òkun, ẹ̀yin ènìyàn ara Kereti; ọ̀rọ̀ Olúwa dojúkọ ọ́, ìwọ Kenaani, ilẹ̀ àwọn ara Filistini. “Èmi yóò pa yín run, ẹnìkan kò sì ní ṣẹ́kù nínú yín.”
6
Ilẹ̀ náà ní etí Òkun, ni ibùgbé àwọn ará Kereti, ni yóò jẹ́ ibùjókòó fún àwọn olùṣọ́-àgùntàn àti agbo àgùntàn.
7
Agbègbè náà yóò sì jẹ́ ti ìyókù àwọn ilé Juda, níbẹ̀ ni wọn yóò sì ti rí koríko fún ẹran. Ní ilé Aṣkeloni ni wọn yóò dùbúlẹ̀ ni àṣálẹ́. Olúwa Ọlọ́run wọn yóò bẹ̀ wọn wò, yóò sì yí ìgbèkùn wọn padà.
Ọ̀rọ̀ Bíbélì: Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™, © 2009, 2017 Biblica, Inc. · CC BY-SA 4.0“Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc., used with permission.
Settings