Skip to content
Sefaniah 1:14-18

Sefaniah 1:14-18

14
“Ọjọ́ ńlá Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀, ó kù sí dẹ̀dẹ̀ ó sì ń yára bọ̀ kánkán. Ẹ tẹ́tí sílẹ̀, ohùn ẹkún àwọn alágbára; ní ọjọ́ Olúwa yóò korò púpọ̀,
15
ọjọ́ náà yóò jẹ́ ọjọ́ ìbínú, ọjọ́ ìrora àti ìpọ́njú, ọjọ́ òfò àti idà ọjọ́ ìdahoro ọjọ́ òkùnkùn àti ìtẹ̀ba, ọjọ́ kurukuru àti òkùnkùn biribiri,
16
ọjọ́ ìpè àti ìpè ogun sí àwọn ìlú olódi àti sí àwọn ilé ìṣọ́ gíga.
17
“Èmi yóò sì mú ìpọ́njú wá sórí ènìyàn, wọn yóò sì máa rìn gẹ́gẹ́ bí afọ́jú, nítorí àwọn ti dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa. Ẹ̀jẹ̀ wọn ni a ó sì tú jáde bí eruku àti ẹran-ara wọn bí ìgbẹ́.
18
Bẹ́ẹ̀ ni fàdákà tàbí wúrà wọn kì yóò sì le gbà wọ́n là ní ọjọ́ ìbínú Olúwa.” Ṣùgbọ́n gbogbo ayé ni a ó fi iná ìjowú rẹ̀ parun, nítorí òun yóò fi ìyára fi òpin sí gbogbo àwọn tí ń gbé ní ilẹ̀ ayé.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options