Skip to content
Ìfihàn 18:2-8

Ìfihàn 18:2-8

2
Ó sì kígbe ní ohùn rara, wí pé: “Babeli ńlá ṣubú! Ó ṣubú! Ó sì di ibùjókòó àwọn ẹ̀mí èṣù, àti ihò fún ẹ̀mí àìmọ́ gbogbo, àti ilé fún ẹyẹ àìmọ́ gbogbo, ilé fún ẹranko ìríra àti àìmọ́ gbogbo.
3
Nítorí nípa ọtí wáìnì ìrunú àgbèrè rẹ̀ ni gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ṣubú. Àwọn ọba ayé sì ti bá a ṣe àgbèrè, àti àwọn oníṣòwò ayé sì di ọlọ́rọ̀ nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọ̀bìà rẹ̀.”
4
Mo sì gbọ́ ohùn mìíràn láti ọ̀run wá, wí pé: “ ‘Ẹ ti inú rẹ̀ jáde, ẹ̀yin ènìyàn mi,’ kí ẹ ma bá a ṣe alábápín nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí ẹ ma bà á sì ṣe gbà nínú ìyọnu rẹ̀.
5
Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ga títí dé ọ̀run, Ọlọ́run sì ti rántí àìṣedéédéé rẹ̀.
6
San an fún un, àní bí òun tí san án fún ní, kí ó sì ṣe e ni ìlọ́po méjì fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀, nínú ago náà tí o ti kún, òun ni kí ẹ sì kún fún un ni méjì.
7
Níwọ́n bí o ti yin ara rẹ̀ lógo tó, tí ó sì hùwà wọ̀bìà, níwọ̀n bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ dá a lóró kí ẹ sì fún un ní ìbànújẹ́; nítorí tí ó wí ní ọkàn rẹ̀ pé, ‘Mo jókòó bí ọbabìnrin, èmi kì sì í ṣe opó, èmí kì yóò sì rí ìbànújẹ́ láé.’
8
Nítorí náà, ní ọjọ́ kan ni ìyọnu rẹ̀ yóò dé, ikú, àti ìbìnújẹ́, àti ìyàn; a ó sì fi iná sun ún pátápátá: nítorí pé alágbára ni Olúwa Ọlọ́run tí ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options