Skip to content
Ìfihàn 16:1-11

Ìfihàn 16:1-11

1
Mo sì gbọ́ ohùn ńlá kan láti inú tẹmpili wá, ń wí fún àwọn angẹli, méje nì pé, “Ẹ lọ, ẹ sì tú ago ìbínú Ọlọ́run wọ̀n-ọn-nì sí orí ayé.”
2
Èkínní sì lọ, ó sì tú ago tirẹ̀ sí orílẹ̀ ayé: egbò kíkẹ̀ tí ó sì díbàjẹ́ sì dá àwọn ènìyàn tí ó ní àmì ẹranko náà, àti àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún àwòrán rẹ̀.
3
Èkejì sì tú ago sínú Òkun; ó sì dàbí ẹ̀jẹ̀ òkú ènìyàn, gbogbo ọkàn alààyè sì kú nínú Òkun.
4
Ẹ̀kẹta sì tú ago tirẹ̀ sínú odò, àti sí orísun àwọn omi; wọ́n sì di ẹ̀jẹ̀.
5
Mo sì gbọ́ angẹli tí ó n wí pé: “Olódodo ni ìwọ ninu gbogbo ìdájọ́ wọ̀nyí, ìwọ ẹni tí ó n bẹ àti tí ó tí wa, Ẹni Mímọ́ nítorí tí ìwọ ṣe ìdájọ́ bẹ́ẹ̀.
6
Nítorí tí wọ́n ti ta ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ àti ti àwọn wòlíì sílẹ̀, ìwọ sì fi ẹ̀jẹ̀ fún wọn mu; èyí yìí ní ó yẹ wọ́n.”
7
Mo sì gbọ́ ti pẹpẹ ń ké wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè, òtítọ́ àti òdodo ní ìdájọ́ rẹ.”
8
Ẹ̀kẹrin sì tú ago tirẹ̀ sórí oòrùn; a sì yọ̀ǹda fún un láti fi iná jó ènìyàn lára.
9
A sì fi ooru ńlá jó àwọn ènìyàn lára, wọ́n sì sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ Ọlọ́run, ẹni tí ó ní agbára lórí ìyọnu wọ̀nyí: wọn kò sì ronúpìwàdà láti fi ògo fún un.
10
Ẹ̀karùnún sì tú ago tirẹ̀ sórí ìtẹ́ ẹranko náà; ilẹ̀ ọba rẹ̀ sì ṣókùnkùn; wọ́n sì ń gé ahọ́n wọn jẹ́ nítorí ìrora.
11
Wọ́n sì sọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run ọ̀run nítorí ìrora wọn àti nítorí egbò wọn, wọ́n kò sì ronúpìwàdà iṣẹ́ wọn.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options