Zum Inhalt springen
Obadiah 1:1-8

Obadiah 1:1-8

1
Ìran ti Obadiah. Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí nípa Edomu. Àwa ti gbọ́ ohùn kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá, a sì ti rán ikọ̀ kan sí gbogbo kèfèrí láti sọ pé, “Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a dìde ogun sí i.”
2
“Kíyèsi i, Èmi yóò sọ ọ́ di kékeré láàrín àwọn kèfèrí; ìwọ yóò sì di gígàn lọ́pọ̀lọ́pọ̀.
3
Ìgbéraga àyà rẹ ti tàn ọ́ jẹ, ìwọ tí ń gbé inú pálapàla àpáta, tí o sì kọ́ ibùgbé rẹ sí ibi gíga, ìwọ wí nínú ọkàn rẹ pé, ‘Ta ni yóò mú mi sọ̀kalẹ̀?’
4
Bí ìwọ tilẹ̀ gbé ara rẹ ga bí ẹyẹ idì, bí ìwọ tilẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ rẹ sí àárín àwọn ìràwọ̀, láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti sọ̀ ọ kalẹ̀,” ni Olúwa wí.
5
“Bí àwọn olè tọ̀ ọ́ wá, bí àwọn ọlọ́ṣà ní òru, Háà! Irú ìparun wo ló dúró dè ọ́, wọn kò ha jalè tó bí wọ́n ti fẹ́? Bí àwọn tí ń ká èso àjàrà tọ̀ ọ́ wá, wọn kò ha ni fi èso àjàrà díẹ̀ sílẹ̀?
6
Báwo ni a ṣe ṣe àwárí nǹkan Esau, tí a sì wá ohun ìní ìkọ̀kọ̀ rẹ̀ jáde.
7
Gbogbo àwọn ẹni ìmùlẹ̀ rẹ ti mú ọ dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ rẹ, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ti tàn ọ́ jẹ, wọ́n sì ti borí rẹ; àwọn tó jẹ oúnjẹ rẹ dẹ pàkúté dè ọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò ní ní òye rẹ̀.”
8
Olúwa wí pé, “Ní ọjọ́ náà, Èmi kì yóò ha pa àwọn ọlọ́gbọ́n Edomu run, àti àwọn amòye run kúrò ní òkè Esau?
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Reading Width 45 chars

Options