Numeri 13:1-20
1
Olúwa sọ fún Mose pé,
2
“Rán ènìyàn díẹ̀ láti lọ yẹ ilẹ̀ Kenaani wò èyí tí mo ti fún àwọn ọmọ Israẹli. Rán ẹnìkọ̀ọ̀kan, tí ó jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.”
3
Mose sì rán wọn jáde láti aginjù Parani gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa. Gbogbo wọn jẹ́ olórí àwọn ènìyàn Israẹli.
4
Orúkọ wọn nìwọ̀nyí: láti inú ẹ̀yà Reubeni, Ṣammua ọmọ Sakkuri;
5
láti inú ẹ̀yà Simeoni, Ṣafati ọmọ Hori;
6
láti inú ẹ̀yà Juda, Kalebu ọmọ Jefunne;
7
láti inú ẹ̀yà Isakari, Igali ọmọ Josẹfu;
8
láti inú ẹ̀yà Efraimu, Hosea ọmọ Nuni;
9
láti inú ẹ̀yà Benjamini, Palti ọmọ Rafu;
10
láti inú ẹ̀yà Sebuluni, Daddieli ọmọ Sodi;
11
láti inú ẹ̀yà Manase (ẹ̀yà Josẹfu), Gaddi ọmọ Susi;
12
láti inú ẹ̀yà Dani, Ammieli ọmọ Gemalli;
13
láti inú ẹ̀yà Aṣeri, Seturu ọmọ Mikaeli.
14
láti inú ẹ̀yà Naftali, Nabi ọmọ Fofsi;
15
láti inú ẹ̀yà Gadi, Geueli ọmọ Maki.
16
Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ènìyàn tí Mose rán láti lọ yẹ ilẹ̀ náà wò. (Hosea ọmọ Nuni ni Mose sọ ní Joṣua.)
17
Nígbà tí Mose rán wọn lọ láti yẹ ilẹ̀ Kenaani wò, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gba ọ̀nà gúúsù lọ títí dé àwọn ìlú olókè.
18
Ẹ wò ó bí ilẹ̀ náà ti rí, bóyá àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà jẹ́ alágbára tàbí aláìlágbára, bóyá wọ́n pọ̀ tàbí wọn kéré.
19
Irú ilẹ̀ wo ni wọ́n gbé? Ṣé ilẹ̀ tó dára ni àbí èyí tí kò dára? Báwo ni ìlú wọn ti rí? Ṣé ìlú olódi ni àbí èyí tí kò ní odi?
20
Báwo ni ilẹ̀ náà ti rí? Ṣé ilẹ̀ ọlọ́ràá ni tàbí aṣálẹ̀? Ṣé igi wà níbẹ̀ àbí kò sí? E sa ipá yín láti rí i pé ẹ mú díẹ̀ nínú èso ilẹ̀ náà wá.” (Ìgbà náà sì jẹ́ àkókò àkọ́pọ́n èso àjàrà gireepu.)
Settings