Nehemiah 7:5-64
5
Nígbà náà ni Ọlọ́run mi fi sí mi ní ọkàn láti kó àwọn ọlọ́lá, àwọn ìjòyè, àti àwọn ènìyàn jọ fún ìforúkọsílẹ̀ ní ìdílé ìdílé. Mo rí ìwé àkọsílẹ̀ ìtàn ìran àwọn tí ó kọ́ gòkè padà wá láti ìgbèkùn. Èyí ni ohun tí mo rí tí a kọ sínú ìwé náà.
6
Èyí ni àwọn ènìyàn agbègbè náà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá láti ìgbèkùn, àwọn tí Nebukadnessari ọba Babeli ti kó ní ìgbèkùn (wọ́n padà sí Jerusalẹmu àti Juda, olúkúlùkù sí ìlú u rẹ̀.
7
Wọ́n jọ rìn wá pẹ̀lú u Serubbabeli, Jeṣua, Nehemiah, Asariah, Raamiah, Nahamani, Mordekai, Bilṣani, Misperi, Bigfai, Nehumu, àti Baanah). Àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn ọkùnrin Israẹli,
8
àwọn ọmọ Paroṣi jẹ́ ẹgbàá ó lé méjìléláàádọ́sàn-án (2,172)
9
Ṣefatia jẹ́ òjìdínnírinwó ó lé méjìlá (372)
10
Arah jẹ́ ẹgbẹ̀tàléláàádọ́ta ó lé méjì (652)
11
Pahati-Moabu (láti ipasẹ̀ ọmọ Jeṣua àti Joabu) jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìnlá ó lé méjìdínlógún (2,818)
12
Elamu jẹ́ àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀fà ó lé mẹ́rin (1,254)
13
Sattu jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀rin ó lé márùn-ún (845)
14
Sakkai jẹ́ òjìdínlẹ́gbẹ̀rin (760)
15
Binnui jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́jọ (648)
16
Bebai jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó lé méjìdínlọ́gbọ̀n (628)
17
Asgadi jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó dín méjìdínlọ́gọ́rin (2,322)
18
Adonikami jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé méje (667)
19
Bigfai jẹ́ ẹgbàá ó lé mẹ́tàdínláàádọ́rin (2,067)
20
Adini jẹ́ àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀ta ó lé márùn-ún (655)
21
Ateri (láti ipasẹ̀ Hesekiah) jẹ́ méjìdínlọ́gọ́rùn-ún (98)
22
Haṣumu jẹ́ ọ̀rìndínnírinwó ó lé mẹ́jọ (328)
23
Besai jẹ́ ọ̀rìndínnírinwó ó lé mẹ́rin (324)
24
Harifu jẹ́ méjìléláàádọ́fà (112)
25
Gibeoni jẹ́ márùndínlọ́gọ́rùn (95).
26
Àwọn ọmọ Bẹtilẹhẹmu àti Netofa jẹ́ igba ó dín méjìlélógún (188)
27
Anatoti jẹ́ méjìdínláàádóje (128)
28
Beti-Asmafeti jẹ́ méjìlélógójì (42)
29
Kiriati-Jearimu, Kefira, àti Beeroti jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin ó lé mẹ́ta (743)
30
Rama àti Geba jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó lé mọ́kànlélógún (621)
31
Mikmasi jẹ́ méjìlélọ́gọ́fà (122)
32
Beteli àti Ai jẹ́ mẹ́tàlélọ́gọ́fà (123)
33
Nebo mìíràn jẹ́ méjìléláàádọ́ta (52)
34
Elamu mìíràn jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó lé mẹ́rìnléláàádọ́ta (1,254)
35
Harimu jẹ́ ọ̀rìndínnírinwó (320)
36
Jeriko jẹ́ ọ̀tàdínnírinwó ó lé márùn-ún (345).
37
Lodi, Hadidi, àti Ono jẹ́ ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀rin ó lé ọ̀kan (721)
38
Senaa jẹ́ ẹgbàajì ó dín àádọ́rin (3,930).
39
Àwọn àlùfáà: àwọn ọmọ Jedaiah (láti ipasẹ̀ ìdílé Jeṣua) jẹ́ ogún dín lẹ́gbẹ̀rin ó dín méje (973)
40
Immeri jẹ́ àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀rún ó lé méjì (1,052)
41
Paṣuri jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó lé mẹ́tàdínláàádọ́ta (1,247)
42
Harimu jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó lé mẹ́tàdínlógún (1,017).
43
Àwọn ọmọ Lefi: àwọn ọmọ Jeṣua (láti ipasẹ̀ Kadmieli, láti ipasẹ̀ Hodafiah) jẹ́ mẹ́rìnléláàádọ́rin (74).
44
Àwọn akọrin: àwọn ọmọ Asafu jẹ́ méjìdínláàádọ́jọ (148).
45
Àwọn aṣọ́nà: àwọn ọmọ Ṣallumu, Ateri, Talmoni, Akkubu, Hatita, àti Ṣobai jẹ́ méjìdínlógóje (138).
46
Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili. Àwọn ọmọ Siha, Hasufa, Tabboati,
47
Kerosi, Sia, Padoni,
48
Lebana, Hagaba, Ṣalmai,
49
Hanani, Giddeli, Gahari,
50
Reaiah, Resini, Nekoda,
51
Gassamu, Ussa, Pasea,
52
Besai, Mehuni, Nefisimu,
53
Bakbu, Hakufa, Harhuri,
54
Basluti, Mehida, Harṣa,
55
Barkosi, Sisera, Tema,
56
Nesia, àti Hatifa.
57
Àwọn ọmọ àwọn ìránṣẹ́ Solomoni: àwọn ọmọ Sotai, Sofereti; Perida,
58
Jaala, Darkoni, Giddeli,
59
Ṣefatia, Hattili, Pokereti-Haṣṣebaimu, àti Amoni.
60
Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti àwọn ọmọ ìránṣẹ́ Solomoni jẹ́ irinwó ó dín mẹ́jọ (392).
61
Àwọn wọ̀nyí gòkè wá láti àwọn ìlú ti Teli-Mela, Teli-Harṣa, Kerubu, Addoni àti Immeri, ṣùgbọ́n wọn kò lè sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé ìdílé àwọn wá láti ara ìran ẹ̀yà Israẹli.
62
Àwọn ọmọ Delaiah, Tobiah àti Nekoda jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀ta ó lé méjì (642).
63
Lára àwọn àlùfáà ni: àwọn ọmọ Hobaiah, Hakosi àti Barsillai (ọkùnrin tí ó fẹ́ ọmọbìnrin Barsillai ará Gileadi, ẹni tí a ń fi orúkọ yìí pè).
64
Àwọn wọ̀nyí wá àkọsílẹ̀ orúkọ ìran wọn, ṣùgbọ́n wọn kò rí í níbẹ̀, fún ìdí èyí, a yọ wọ́n kúrò nínú àwọn tí ń ṣiṣẹ́ àlùfáà gẹ́gẹ́ bí aláìmọ́.
Settings