Skip to content
Marku 3:1-14

Marku 3:1-14

1
Nígbà tí Jesu wá sí Sinagọgu. Sì kíyèsi i ọkùnrin kan wà níbẹ̀, tí ọwọ́ rẹ̀ kan rọ.
2
Àwọn kan nínú wọn sì ń wa ọ̀nà láti fi ẹ̀sùn kan Jesu. Nítorí náà, wọ́n ń ṣọ́ Ọ bí yóò mú un láradá ní ọjọ́ ìsinmi.
3
Jesu wí fún ọkùnrin tí ọwọ́ rẹ̀ rọ náà pé, “Dìde dúró ní iwájú ìjọ ènìyàn.”
4
Nígbà náà ni Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ǹjẹ́ ó bá òfin mu ní ọjọ́ ìsinmi bóyá láti ṣe rere, tàbí láti ṣe búburú! Láti gbà ẹ̀mí là, tàbí pa á run?” Ṣùgbọ́n wọ́n dákẹ́ láìfèsì.
5
Nígbà tí ó sì wo gbogbo wọn yíká pẹ̀lú ìbínú, ọkàn rẹ̀ sì bàjẹ́ nítorí líle àyà wọn, ó sọ fún ọkùnrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ jáde.” Ó nà án jáde, ọwọ́ náà sì bọ̀ sípò padà pátápátá.
6
Lójúkan náà, àwọn Farisi jáde lọ, láti bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Herodu gbìmọ̀ pọ̀, bí wọn yóò ṣe pa Jesu.
7
Jesu pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ yẹra kúrò níbẹ̀ lọ sí etí Òkun. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láti Galili àti Judea sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.
8
Nígbà tí wọ́n gbọ́ ìròyìn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì tọ̀ ọ́ wá láti Judea, Jerusalẹmu àti Idumea, àti láti apá kejì odò Jordani àti láti ìhà Tire àti Sidoni.
9
Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn, Jesu sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti ṣètò ọkọ̀ ojú omi kékeré kan sílẹ̀ fún un láti lọ, láti lé àwọn èrò sẹ́yìn.
10
Nítorí tí ó mú ọ̀pọ̀ ènìyàn láradá, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn aláìsàn ló bí ara wọn lù ú láti fi ọwọ́ kàn án.
11
Ìgbàkúgbà tí àwọn tí ó ni ẹ̀mí àìmọ́ bá ti fojú ri, wọ́n á wólẹ̀ níwájú rẹ̀. Wọn a sì kígbe lóhùn rara wí pé, “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run.”
12
Ṣùgbọ́n ó kìlọ̀ fún wọn gidigidi, kí wọn má ṣe fi òun hàn.
13
Jesu gun orí òkè lọ, ó sì pe àwọn kan tí ó yàn láti wà pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá.
14
Ó yan àwọn méjìlá, kí wọn kí ó lè wà pẹ̀lú rẹ̀, àti kí ó lè rán wọn lọ láti wàásù
Settings

Reading style

Typeface

Font size 19px

Reading width 75 chars

Options