Marku 10:1-12
1
Nígbà náà, Jesu kúrò níbẹ̀, ó sì wá sí ẹkùn Judea níhà òkè odò Jordani. Àwọn ènìyàn sì tún tọ̀ ọ́ wá, bí i ìṣe rẹ̀, ó sì kọ́ wọn.
2
Àwọn Farisi kan tọ̀ ọ́ wá, láti dán an wò. Wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ ó ha tọ̀nà fún ènìyàn láti kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀?”
3
Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ni Mose pàṣẹ fún un yín?”
4
Wọ́n dáhùn pé, “Mose yọ̀ǹda fún wa láti kọ ìwé ìkọ̀sílẹ̀ fún un, kí a sì fi sílẹ̀.”
5
Ṣùgbọ́n Jesu dá wọn lóhùn, ó sì wí pé, “Nítorí líle àyà yín ni Mose fi kọ òfin yìí fun un yín.
6
Ṣùgbọ́n láti ìgbà tí ayé ti ṣẹ̀, Ọlọ́run dá wọn ní akọ àti abo.
7
Nítorí ìdí èyí, ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀ yóò sì fi ara mọ́ aya rẹ̀.
8
Òun àti ìyàwó rẹ̀ yóò di ara kan náà. Nítorí náà, wọn kì í túnṣe méjì mọ́ bí kò ṣe ẹyọ ọ̀kan ṣoṣo.
9
Nítorí náà ohun ti Ọlọ́run bá sọ dọ̀kan, ki ẹnikẹ́ni máa ṣe yà wọ́n.”
10
Lẹ́yìn náà, nígbà tí Jesu nìkan wà nínú ilé pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n tún béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ nípa ohun kan náà.
11
Jesu túbọ̀ ṣe àlàyé fún wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ tí ó bá sì fẹ́ ẹlòmíràn, irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ ṣe panṣágà sí obìnrin tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé níyàwó.
12
Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, bí obìnrin kan bá kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì fẹ́ ọkùnrin mìíràn, irú obìnrin bẹ́ẹ̀ ṣe panṣágà.”
Settings