Luku 23:1-12
1
Gbogbo ìjọ ènìyàn sì dìde, wọ́n sì fà á lọ sí ọ̀dọ̀ Pilatu.
2
Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹ̀sùn kàn án, wí pé, “Àwa rí ọkùnrin yìí ó ń yí orílẹ̀-èdè wa lọ́kàn padà, ó sì ń dá wọn lẹ́kun láti san owó òde fún Kesari, ó ń wí pé, òun tìkára òun ni Kristi ọba.”
3
Pilatu sì bi í léèrè, wí pé, “Ìwọ ha ni ọba àwọn Júù?” Ó sì dá a lóhùn wí pé, “Ìwọ wí i.”
4
Pilatu sì wí fún àwọn olórí àlùfáà àti fún ìjọ ènìyàn pé, “Èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ ọkùnrin yìí.”
5
Wọ́n sì túbọ̀ tẹnumọ́ ọn pé, “Ó ń ru ènìyàn sókè, ó ń kọ́ni káàkiri gbogbo Judea, ó bẹ̀rẹ̀ láti Galili títí ó fi dé ìhín yìí!”
6
Nígbà tí Pilatu gbọ́ orúkọ Galili, ó béèrè bí ọkùnrin náà bá jẹ́ ará Galili.
7
Nígbà tí ó sì mọ̀ pé ará ilẹ̀ abẹ́ àṣẹ Herodu ni, ó rán an sí Herodu, ẹni tí òun tìkára rẹ̀ wà ní Jerusalẹmu ní àkókò náà.
8
Nígbà tí Herodu, sì rí Jesu, ó yọ̀ gidigidi; nítorí tí ó ti ń fẹ́ rí i pẹ́ ó sá à ti ń gbọ́ ìròyìn púpọ̀ nítorí rẹ̀; ó sì ń retí láti rí i kí iṣẹ́ àmì díẹ̀ ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe.
9
Ó sì béèrè ọ̀rọ̀ púpọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀; ṣùgbọ́n kò da a lóhùn rárá.
10
Àti àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé dúró, wọ́n sì ń fi ẹ̀sùn kàn án gidigidi.
11
Àti Herodu pẹ̀lú àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, wọ́n kẹ́gàn rẹ̀, wọ́n sì ń fi í ṣẹ̀sín, wọ́n wọ̀ ọ́ ní aṣọ dáradára, ó sì rán an padà tọ Pilatu lọ.
12
Pilatu àti Herodu di ọ̀rẹ́ ara wọn ní ọjọ́ náà, nítorí látijọ́ ọ̀tá ara wọn ni wọ́n ti jẹ́ rí.
Settings