Joṣua 19:1-9
1
Kèké kejì jáde fún ẹ̀yà Simeoni, ní agbo ilé, ní agbo ilé. Ìní wọn sì wà ní àárín ilẹ̀ Juda.
2
Lára ìpín wọn ní: Beerṣeba (tàbí Ṣeba), Molada,
3
Hasari-Ṣuali, Bala, Esemu,
4
Eltoladi, Betuli, Horma,
5
Siklagi, Beti-Markaboti, Hasari Susa,
6
Beti-Lebaoti àti Ṣarueli, ìlú wọn jẹ́ mẹ́tàlá àti ìletò wọn.
7
Aini, Rimoni, Eteri àti Aṣani, ìlú wọn jẹ́ mẹ́rin àti ìletò wọn,
8
àti gbogbo àwọn agbègbè ìlú wọ̀nyí títí dé Baalati-Beeri (Rama ní gúúsù). Èyí ni ilẹ̀ ìní ẹ̀yà àwọn ọmọ Simeoni, agbo ilé, ní agbo ilé.
9
A mú ogún ìní àwọn ọmọ Simeoni láti ìpín Juda, nítorí ìpín Juda pọ̀ ju èyí tí wọ́n nílò lọ. Báyìí ni àwọn ọmọ Simeoni gba ìní wọn ní àárín ilẹ̀ Juda.
Settings