Johanu 5:12-26
12
Nígbà náà ni wọ́n bi í lérè wí pé, “Ọkùnrin wo ni ẹni tí ó wí fún ọ pé gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn?”
13
Ẹni tí a mú láradá náà kò sì mọ̀ ẹni tí ó jẹ́ nítorí Jesu ti kúrò níbẹ̀, àwọn ènìyàn púpọ̀ wà níbẹ̀.
14
Lẹ́yìn náà, Jesu rí i nínú tẹmpili ó sì wí fún un pé, “Wò ó, a mú ọ láradá: má ṣe dẹ́ṣẹ̀ mọ́, kí ohun tí ó burú ju èyí lọ má ba à bá ọ!”
15
Ọkùnrin náà lọ, ó sì sọ fún àwọn Júù pé, Jesu ni ẹni tí ó mú òun láradá.
16
Nítorí èyí ni àwọn Júù ṣe inúnibíni sí Jesu, wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa á, nítorí tí o ń ṣe nǹkan wọ̀nyí ní ọjọ́ ìsinmi.
17
Ṣùgbọ́n Jesu dá wọn lóhùn pé, “Baba mi ń ṣiṣẹ́ títí di ìsinsin yìí, èmi náà sì ń ṣiṣẹ́.”
18
Nítorí èyí ni àwọn Júù túbọ̀ ń wá ọ̀nà láti pa á, kì í ṣe nítorí pé ó ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́ nìkan ni, ṣùgbọ́n ó wí pẹ̀lú pé, Baba òun ni Ọlọ́run jẹ́, ó ń mú ara rẹ̀ bá Ọlọ́run dọ́gba.
19
Nígbà náà ni Jesu dáhùn, ó sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọmọ kò lè ṣe ohunkóhun fún ara rẹ̀, bí kò ṣe ohun tí ó bá rí pé Baba ń ṣe, nítorí ohunkóhun tí baba bá ń ṣe, ìwọ̀nyí ni ọmọ náà sì ń ṣe pẹ̀lú.
20
Nítorí Baba fẹ́ràn ọmọ, ó sì ti fi ohun gbogbo tí ó ń ṣe hàn án, òun yóò sì fi iṣẹ́ tí ó tóbi jù wọ̀nyí lọ hàn án, kí ẹnu lè yà yín.
21
Nítorí pé, gẹ́gẹ́ bí Baba ti ń jí òkú dìde, tí ó sì ń sọ wọ́n di alààyè: bẹ́ẹ̀ ni ọmọ ń sọ àwọn tí ó fẹ́ di alààyè pẹ̀lú.
22
Nítorí pé Baba kì í ṣe ìdájọ́ ẹnikẹ́ni, ṣùgbọ́n ó ti fi gbogbo ìdájọ́ lé ọmọ lọ́wọ́,
23
kí gbogbo ènìyàn lè máa fi ọlá fún ọmọ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń fi ọlá fún Baba. Ẹnikẹ́ni tí kò bá fi ọlá fún ọmọ, kò fi ọlá fún Baba tí ó ran an.
24
“Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí ó bá sì gba ẹni tí ó rán mi gbọ́, ó ní ìyè tí kò nípẹ̀kun, òun kì yóò sì wá sí ìdájọ́; ṣùgbọ́n ó ti ré ikú kọjá bọ́ sí ìyè.
25
Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, wákàtí náà ń bọ̀, ó sì dé tán nísinsin yìí, nígbà tí àwọn òkú yóò gbọ́ ohùn Ọmọ Ọlọ́run, àwọn tí ó bá gbọ́ yóò sì yè.
26
Nítorí pé gẹ́gẹ́ bí Baba ti ní ìyè nínú ara rẹ̀; gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ó sì fi fún ọmọ láti ní ìyè nínú ara rẹ̀;
Settings