Skip to content
Jobu 15:17-35

Jobu 15:17-35

17
“Èmi ó fihàn ọ́, gbọ́ ti èmi; èyí tí èmi sì rí, òun ni èmi ó sì sọ,
18
ohun tí àwọn ọlọ́gbọ́n ti pa ní ìtàn láti ọ̀dọ̀ àwọn baba wọn wá, ti wọ́n kò sì fi pamọ́.
19
Àwọn tí a fi ilẹ̀ ayé fún nìkan, ti àlejò kan kò sì là wọ́n kọjá.
20
Ènìyàn búburú ń ṣe làálàá, pẹ̀lú ìrora, ní ọjọ́ rẹ̀ gbogbo, àti iye ọdún ní a dá sílẹ̀ fún aninilára.
21
Ìró ìbẹ̀rù ń bẹ ní etí rẹ̀; nínú ìrora ni apanirun yóò dìde sí i.
22
Kò gbàgbọ́ pé òun ó jáde kúrò nínú òkùnkùn; a sì ṣà á sápá kan fún idà.
23
Ó ń wò káàkiri fún oúnjẹ wí pé, níbo ní ó wà? Ó mọ̀ pé ọjọ́ òkùnkùn súnmọ́ tòsí.
24
Ìpọ́njú pẹ̀lú ìrora ọkàn yóò mú un bẹ̀rù, wọ́n ó sì ṣẹ́gun rẹ̀ bi ọba ti ìmúra ogun.
25
Nítorí pé ó ti nawọ́ rẹ̀ jáde lòdì sí Ọlọ́run, ó sì múra rẹ̀ le lòdì sí Olódùmarè,
26
ó súre, ó sì fi ẹ̀yìn gíga, àní fi ike-kókó àpáta rẹ̀ tí ó nípọn kọlù ú.
27
“Nítorí tí òun fi ọ̀rá rẹ̀ bo ara rẹ̀ lójú, o sì ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹran sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.
28
Òun sì gbé inú ahoro ìlú, àti nínú ilẹ̀ tí ènìyàn kò gbé mọ́, tí ó múra tán láti di àlàpà.
29
Òun kò lé di ọlọ́rọ̀, bẹ́ẹ̀ ohun ìní rẹ̀ kò lè dúró pẹ́; bẹ́ẹ̀ kò lè mú pípé rẹ̀ dúró pẹ́ lórí ilẹ̀.
30
Òun kì yóò jáde kúrò nínú òkùnkùn; ọ̀wọ́-iná ni yóò jó ẹ̀ka rẹ̀, àti nípasẹ̀ ẹ̀mí ẹnu Ọlọ́run ní a ó gba kúrò.
31
Kí òun kí ó má ṣe gbẹ́kẹ̀lé asán, kí ó má sì ṣe tan ara rẹ̀ jẹ. Nítorí pé asán ní yóò jásí èrè rẹ̀.
32
A ó mú un ṣẹ ṣáájú pípé ọjọ́ rẹ̀, ẹ̀ka rẹ̀ kì yóò sì tutù.
33
Yóò dàbí àjàrà tí a gbọn èso àìpọ́n rẹ̀ dànù, yóò sì rẹ̀ ìtànná rẹ̀ dànù bí i ti igi Olifi.
34
Nítorí pé ayọ̀ àwọn àgàbàgebè yóò túká, iná ní yóò sì jó àgọ́ àwọn tí ó fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀.
35
Wọ́n lóyún ìwà ìkà, wọ́n sì bí ẹ̀ṣẹ̀, ikùn wọn sì pèsè ẹ̀tàn.”
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options