Skip to content
Jeremiah 44:1-14

Jeremiah 44:1-14

1
Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá nípa àwọn Júù tí ń gbé ní ìsàlẹ̀ Ejibiti ní Migdoli, Tafanesi àti Memfisi àti ní apá òkè Ejibiti:
2
“Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí: Wo ibi tí mo mú bá Jerusalẹmu àti gbogbo ìlú Juda. Lónìí, wọ́n wà ní ìyapa àti ìparun.
3
Nítorí pé ibi tí wọ́n ti ṣe. Wọ́n mú mi bínú nípa tùràrí fínfín àti nípa bíbọ àwọn òrìṣà, yálà èyí tí ìwọ tàbí àwọn baba rẹ kò mọ̀.
4
Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ní mo rán wòlíì mi, èyí tí ó wí báyìí pé, ‘Má ṣe àwọn ohun ìríra yìí tí èmi kórìíra.’
5
Ṣùgbọ́n wọn kò fetísílẹ̀ láti fi ọkàn si. Wọn kò sì yípadà kúrò nínú búburú wọn tàbí dáwọ́ ẹbọ sísun sí àwọn òrìṣà dúró.
6
Fún ìdí èyí, ìbínú gbígbóná mi ni èmi yóò yọ sí àwọn ìlú Juda àti òpópó Jerusalẹmu àti sísọ wọ́n di ìparun bí ó ṣe wà lónìí yìí.
7
“Báyìí tún ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun Israẹli wí, kí ló dé tí ẹ fi ń mu ibi ńlá yìí wá sí orí ara yín nípa yíyapa kúrò lára Juda ọkùnrin àti obìnrin, ọmọdé àti èwe, tí ẹ kò sì ku ọ̀kankan?
8
Èéṣe tí ẹ fi mú mi bínú pẹ̀lú ohun tí ọwọ́ yín ṣe pẹ̀lú ẹbọ sísun sí àwọn òrìṣà Ejibiti, níbi tí ẹ wá láti máa gbé? Ẹ̀ ò pa ara yín run, ẹ̀ ó sì sọ ara yín di ẹni ìfiré àti ẹ̀gàn láàrín àwọn orílẹ̀-èdè ayé gbogbo.
9
Ṣé ẹ̀yin ti gbàgbé ibi tí àwọn baba ńlá yín àti àwọn ọba; àwọn ayaba Juda, àti àwọn ibi tí ẹ ti ṣe àti àwọn ìyàwó yín ní ilẹ̀ Juda àti ní òpópó Jerusalẹmu?
10
Láti ìgbà náà sí àkókò yìí, wọn kò rẹ ara wọn sílẹ̀ tàbí fi ìtẹríba hàn tàbí kí wọn ó tẹ̀lé òfin àti àṣẹ tí mo pa fún un yín àti àwọn baba yín.
11
“Fún ìdí èyí, báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run àwọn Israẹli wí: Mo ti pinnu láti mú ibi wá sí orí yín àti láti pa Juda run.
12
Èmi yóò sì mú àwọn èérún tí ó kù ní Juda, tí wọ́n ṣetán láti lọ Ejibiti. Wọn yóò ṣubú pẹ̀lú idà tàbí kí wọn kú pẹ̀lú ìyàn láti orí ọmọdé títí dé àgbà ni wọn yóò kú láti ọwọ́ ìyàn tàbí idà. Wọn yóò di ẹni ìfiré àti ìparun, ẹni ẹ̀kọ̀ àti ẹni ẹ̀gàn.
13
Èmi yóò fi ìyà jẹ ẹni tí ó bá ń gbé ní Ejibiti pẹ̀lú idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn bí mo ṣe fi ìyà jẹ Jerusalẹmu.
14
Kò sí èyí tí ó kéré jù nínú Juda tí ó kù, tí ó ń gbé ilẹ̀ Ejibiti tí yóò sá àsálà padà sórí ilẹ̀ Juda, èyí tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ láti padà sí, àti láti máa gbé; àyàfi àwọn aṣàtìpó mélòó kan.”
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options