Isaiah 5:16-30
16
Ṣùgbọ́n Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni a ó gbéga nípa ẹ̀tọ́ rẹ̀, Ọlọ́run ẹni mímọ́ yóò sì fi ara rẹ̀ hàn ní mímọ́ nípa òdodo rẹ̀.
17
Nígbà náà ni àwọn àgùntàn yóò máa jẹ́ ko ní ibùgbé e wọn, àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn yóò máa jẹ nínú ahoro àwọn ọlọ́rọ̀.
18
Ègbé ni fún àwọn tí ń fi ohun asán fa ẹ̀ṣẹ̀, àti àwọn tí o dàbí ẹni pé wọ́n ń fi okùn kẹ̀kẹ́ ẹ̀sìn fa ẹsẹ̀,
19
sí àwọn tí ó sọ pé, “Jẹ́ kí Ọlọ́run ṣe kíákíá, jẹ́ kí ó yára ṣiṣẹ́ rẹ̀ kí a lè rí i, jẹ́ kí ó súnmọ́ bí jẹ́ kí ètò ẹni mímọ́ Israẹli kí ó dé, kí àwa kí ó le mọ̀ ọ́n.”
20
Ègbé ni fún àwọn tí ń pe ibi ní rere, àti rere ní ibi, tí ń fi òkùnkùn ṣe ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ́lẹ̀ ṣe òkùnkùn, tí ń fi ìkorò ṣe adùn àti adùn ṣe ìkorò.
21
Ègbé ni fún àwọn tí ó gbọ́n lójú ara wọn tí wọ́n jáfáfá lójú ara wọn.
22
Ègbé ni fún àwọn akọni nínú wáìnì mímu àti àwọn akíkanjú nínú àdàlú ọtí,
23
tí wọ́n dá ẹlẹ́bi sílẹ̀ nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀, tí wọn sì du aláre ní ẹ̀tọ́.
24
Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí ahọ́n iná ṣe ń jó àgékù koríko run àti bí koríko ṣe rẹlẹ̀ wẹ̀sì nínú iná, bẹ́ẹ̀ ni egbò wọn yóò jẹrà tí òdodo wọn yóò sì fẹ́ lọ bí eruku: nítorí pé wọ́n ti kọ òfin Olúwa àwọn ọmọ-ogun sílẹ̀ wọ́n sì gan ọ̀rọ̀ Ẹni mímọ́ Israẹli.
25
Nítorí náà, ìbínú Olúwa gbóná si àwọn ènìyàn rẹ̀, ó ti gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ó sì lù wọ́n bolẹ̀. Àwọn òkè sì wárìrì, òkú wọn sì dàbí ààtàn ní àárín ìgboro. Pẹ̀lú gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò, ṣùgbọ́n ọ̀wọ́ rẹ̀ sì ná jáde síbẹ̀.
26
Yóò sì gbé ọ̀págun sókè sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó jìnnà, yóò sì kọ sí wọn tí ó wà ní ìpẹ̀kun ilẹ̀. Sì kíyèsi, wọ́n yóò yára wá kánkán.
27
Kò sí ẹni tí yóò rẹ̀ nínú wọn, tàbí tí yóò kọsẹ̀, kò sí ẹni tí yóò tòògbé tàbí tí yóò sùn; bẹ́ẹ̀ ni àmùrè ẹ̀gbẹ́ wọn kì yóò tú, bẹ́ẹ̀ ni okùn sálúbàtà wọn kì yóò ja.
28
Àwọn ọfà wọn múná, gbogbo ọrun wọn sì le; pátákò àwọn ẹṣin wọn le bí òkúta akọ, àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ wọn sì dàbí ìjì líle.
29
Bíbú wọn dàbí tí kìnnìún, wọ́n bú bí ẹgbọrọ kìnnìún, wọ́n ń kọ bí wọ́n ti di ẹran ọdẹ wọn mú tí wọn sì gbé e lọ láìsí ẹni tí yóò gbà á là.
30
Ní ọjọ́ náà, wọn yóò hó lé e lórí gẹ́gẹ́ bí i rírú omi Òkun. Bí ènìyàn bá sì wo ilẹ̀, yóò rí òkùnkùn àti ìbànújẹ́; pẹ̀lúpẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ yóò di òkùnkùn pẹ̀lú kurukuru rẹ̀.
Ọ̀rọ̀ Bíbélì: Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™, © 2009, 2017 Biblica, Inc. · CC BY-SA 4.0“Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc., used with permission.
Settings