Gẹnẹsisi 10:6-20
6
Àwọn ọmọ Hamu ni: Kuṣi, Ejibiti, Puti àti Kenaani.
7
Àwọn ọmọ Kuṣi ni: Seba, Hafila, Sabta, Raama, àti Sabteka. Àwọn ọmọ Raama ni: Ṣeba àti Dedani.
8
Kuṣi sì bí Nimrodu, ẹni tí ó di alágbára jagunjagun ní ayé.
9
Ó sì jẹ́ ògbójú ọdẹ níwájú Olúwa; nítorí náà ni a ṣe ń wí pé, “Bí Nimrodu, ògbójú ọdẹ níwájú Olúwa.”
10
Ìjọba rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni Babeli, Ereki, Akkadi, Kalne, gbogbo wọn wà ní ilẹ̀ Ṣinari.
11
Láti ilẹ̀ náà ni ó ti lọ sí Asiria, níbi tí ó ti tẹ ìlú Ninefe, Rehoboti àti Kala,
12
àti Resini, tí ó wà ní àárín Ninefe àti Kala, tí ó jẹ́ ìlú olókìkí.
13
Ejibiti sì bí Ludimu, Anamimu, Lehabimu, Naftuhimu.
14
Patrusimu, Kasluhimu (láti ọ̀dọ̀ ẹni tí àwọn ará Filistini ti wá) àti àwọn ará Kaftorimu.
15
Kenaani sì bí Sidoni àkọ́bí rẹ̀, àti Heti.
16
Àti àwọn ará Jebusi, àti àwọn ará Amori, àti àwọn ará Girgaṣi,
17
àti àwọn ará Hifi, àti àwọn ará Arki, àti àwọn ará Sini,
18
àti àwọn ará Arfadi, àti àwọn ará Semari, àti àwọn ará Hamati. Lẹ́yìn èyí ni àwọn ẹ̀yà Kenaani tànkálẹ̀.
19
Ààlà ilẹ̀ àwọn ará Kenaani sì dé Sidoni, lọ sí Gerari títí dé Gasa, lọ sí Sodomu, Gomorra, Adma àti Seboimu, títí dé Laṣa.
20
Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Hamu, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, àti èdè wọn, ní ìpínlẹ̀ wọn àti ní orílẹ̀-èdè wọn.
Settings