Esekiẹli 48:8-14
8
“Ní agbègbè Juda, láti ìhà ìlà-oòrùn dé ìhà ìwọ̀-oòrùn ni yóò jẹ́ ìpín tí ìwọ yóò gbé kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn pàtàkì. Èyí tí yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ (25,000) ní ìbú, gígùn rẹ̀ láti ìlà-oòrùn lọ sí ìwọ̀-oòrùn yóò jẹ́ bákan náà bí ọ̀kan nínú àwọn ìpín ìyókù; láti ìhà ìlà-oòrùn dé ìhà ìwọ̀-oòrùn, ibi mímọ́ yóò sì wà ní àárín gbùngbùn rẹ̀.
9
“Ìpín pàtàkì tí ìwọ yóò fi fún Olúwa yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ní gígùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ ni ìbú.
10
Èyí yóò jẹ́ ìpín ibi mímọ́ fún àwọn àlùfáà. Èyí yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn ní ìhà àríwá, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ ni ìhà ìlà-oòrùn, ó sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn ní ìhà gúúsù. Ní àárín gbùngbùn rẹ̀ ní ilé fún Olúwa yóò wà.
11
Èyí yóò wà fún àwọn àlùfáà tí a yà sí mímọ́, àwọn ọmọ Sadoku tí wọn jẹ́ olóòtítọ́ nínú sí sìn mí, tiwọn kò sì ṣáko lọ bí ti àwọn Lefi ṣe ṣe nígbà tí àwọn Israẹli ṣáko lọ.
12
Èyí yóò jẹ́ ọrẹ pàtàkì fún wọn láti ara ìpín ibi mímọ́ ilẹ̀ náà, ìpín tí ó jẹ́ mímọ́ jùlọ, tí ó jẹ́ ààlà agbègbè àwọn Lefi.
13
“Ní àkọjúsí agbègbè àwọn àlùfáà, àwọn Lefi yóò pín ìpín kan tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú. Gígùn rẹ̀ ní àpapọ̀ yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́, àti inú rẹ̀ yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́.
14
Wọn kò gbọdọ̀ tà tàbí pààrọ̀ ọ̀kankan nínú rẹ̀. Èyí yìí ni ó dára jùlọ lára ilẹ̀ náà, a kò sì gbọdọ̀ fi fún ẹlòmíràn nítorí pé ó jẹ́ mímọ́ fún Olúwa.
Settings