Skip to content
Daniẹli 4:1-17

Daniẹli 4:1-17

1
Nebukadnessari ọba, sí gbogbo ènìyàn, orílẹ̀ àti onírúurú èdè, tí ó ń gbé ní àgbáyé. Kí àlàáfíà máa pọ̀ sí i fún un yín. Kí ẹ ṣe rere tó pọ̀!
2
Ó jẹ́ ìdùnnú fún mi láti fi iṣẹ́ àmì àti ìyanu tí Ọlọ́run Ọ̀gá-Ògo ti ṣe fún mi hàn.
3
Báwo ni àmì rẹ̀ ti tóbi tó,
4
Èmi Nebukadnessari wà ní ààfin mi, pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn àti àlàáfíà.
5
Mo lá àlá kan èyí tí ó bà mí lẹ́rù. Nígbà tí mo wà lórí ibùsùn mi, ìran tí ó jáde lọ́kàn mi dẹ́rùbà mí.
6
Nígbà náà, ni mo pàṣẹ pé kí a mú gbogbo àwọn amòye Babeli wá, kí wọn wá sọ ìtumọ̀ àlá náà fún mi.
7
Nígbà tí àwọn apidán, àwọn apògèdè, àwọn awòràwọ̀ àti àwọn aláfọ̀ṣẹ wá, mo sọ àlá náà fún wọn, ṣùgbọ́n wọn kò le è sọ ìtumọ̀ àlá náà fún mi.
8
Ní ìkẹyìn Daniẹli wá síwájú mi, mo sì sọ àlá náà fún. (Ẹni tí à ń pè ní Belṣassari gẹ́gẹ́ bí orúkọ òrìṣà mi àti pé ẹ̀mí àwọn ọlọ́run mímọ́ wà nínú rẹ̀.)
9
Mo wí pé, “Belṣassari, olórí àwọn amòye, èmi mọ̀ wí pé ẹ̀mí ọlọ́run mímọ́ wà nínú rẹ, kò sì ṣí àṣírí kan tí ó ṣòro jù fún ọ. Sọ àlá mi kí o sì túmọ̀ rẹ̀ fún mi.
10
Èyí ni ìran náà tí mo rí nígbà tí mo wà lórí ibùsùn mi, mo rí igi kan láàrín ayé, igi náà ga gidigidi.
11
Igi náà tóbi, ó sì lágbára, orí rẹ̀ sì ń kan ọ̀run; a sì rí i títí dé òpin ayé.
12
Ewé rẹ̀ lẹ́wà, èso rẹ̀ sì pọ̀, ó sì ń pèsè oúnjẹ fún gbogbo ènìyàn. Abẹ́ ẹ rẹ̀ ni àwọn ẹranko igbó fi ṣe ibùgbé, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ń gbé ní ẹ̀ka rẹ̀, nínú rẹ̀ ni gbogbo alààyè ti ń jẹ.
13
“Lórí ibùsùn mi, mo rí ìran náà, olùṣọ́ kan dúró síwájú u mi, àní ẹni mímọ́ kan, ó ń bọ̀ wá láti ọ̀run
14
ó kígbe sókè wí pé, ‘Gé igi náà kí o sì gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kúrò; gbọn ewé rẹ̀ ká, kí o sì fọ́n èso rẹ̀ dànù. Jẹ́ kí àwọn ẹranko tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ sá àti àwọn ẹyẹ tí ó wà ní ẹ̀ka rẹ̀ kúrò.
15
Ṣùgbọ́n fi kùkùté àti gbòǹgbò rẹ̀ tí a fi irin àti idẹ dè ṣẹ́kù sórí ilẹ̀ àti sí orí koríko igbó. “ ‘Jẹ́ kí ìrì ọ̀run sẹ̀ sí i lára, kí ó sì jẹ́ kí ìpín in rẹ̀ wà pẹ̀lú àwọn ẹranko igbó láàrín ilẹ̀ ayé.
16
Jẹ́ kí ọkàn rẹ̀ kí ó yí padà kúrò ní ti ènìyàn, kí a sì fún un ní ọkàn ẹranko, títí ìgbà méje yóò fi kọjá lórí i rẹ̀.
17
“ ‘Olùṣọ́ ni ó gbé ìpinnu náà jáde, àṣẹ sì wá láti ọ̀dọ̀ ẹni mímọ́, kí gbogbo alààyè le mọ̀ wí pé, Ọ̀gá-ògo ni olórí ìjọba ènìyàn, ó sì ń fi fún ẹnikẹ́ni tí ó wù ú, òun sì ń gbé onírẹ̀lẹ̀ lórí i wọn.’
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options