Skip to content
Daniẹli 11:2-9

Daniẹli 11:2-9

2
“Ní ìsinsin yìí, mo sọ òtítọ́ fún ọ ọba mẹ́ta yóò dìde sí i ní Persia, àti ẹ̀kẹrin tí yóò jẹ́ ọlọ́rọ̀ ju gbogbo wọn lọ. Tí ó bá ti di alágbára nípa ọrọ̀ rẹ̀, yóò sì ru gbogbo wọn sókè lòdì sí ìjọba Giriki.
3
Nígbà náà ni ọba alágbára kan yóò fi ara hàn, yóò ṣe àkóso pẹ̀lú agbára ńlá, yóò sì ṣe bí ó ti wù ú.
4
Lẹ́yìn ìgbà tí ó bá fi ara hàn tán, ìjọba rẹ̀ yóò fọ́, yóò sì pín sí mẹ́rin ní orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé, ìjọba náà kò sì ṣọ́wọ́ àwọn ìran rẹ̀ tàbí kí ó ní agbára tí ó ń lò tẹ́lẹ̀, nítorí, a ó fa ìjọba rẹ̀ tu a ó sì fi fún àwọn mìíràn.
5
“Ọba ìhà gúúsù yóò di alágbára ṣùgbọ́n ọ̀kan lára àwọn aláṣẹ rẹ̀ yóò di alágbára jù ú lọ, yóò sì ṣe àkóso ìjọba rẹ̀ pẹ̀lú agbára ńlá.
6
Lẹ́yìn ọdún púpọ̀ wọn yóò dá májẹ̀mú àlàáfíà, ọmọbìnrin ọba gúúsù yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ọba àríwá láti bá a dá májẹ̀mú àlàáfíà, ṣùgbọ́n òun kì yóò lè di agbára apá a rẹ̀ mú, bẹ́ẹ̀ ni òun kì yóò lè dádúró, ṣùgbọ́n a ó tẹrí i rẹ̀ ba àti àwọn tí ó mú un wá, àti ọmọ tí ó bí, àti ẹni tí ó ń mu lọ́kàn le ní gbogbo àkókò wọ̀nyí.
7
“Ọ̀kan lára àwọn ìdílé e rẹ̀, ọmọbìnrin ọba gúúsù yóò dìde láti gba ipò o rẹ̀. Yóò sì kọlu ogun ọba àríwá, yóò sì wó odi alágbára; yóò bá wọn jà yóò sì borí.
8
Yóò gba òrìṣà wọn, ère dídá àti ohun èlò oníye lórí ti fàdákà àti ti wúrà, yóò sì kó wọn lọ sí Ejibiti. Fún ọdún díẹ̀ yóò fi ọba àríwá lọ́rùn sílẹ̀.
9
Nígbà náà, ni ọba àríwá yóò gbógun ti ilẹ̀ ọba, gúúsù, ṣùgbọ́n yóò padà sí Orílẹ̀-èdè, òun fúnra rẹ̀.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options