Skip to content
Ìṣe àwọn Aposteli 4:27-37

Ìṣe àwọn Aposteli 4:27-37

27
Àní nítòótọ́ ní Herodu àti Pọntiu Pilatu, pẹ̀lú àwọn aláìkọlà àti àwọn ènìyàn Israẹli kó ara wọn jọ ní ìlú yìí láti dìtẹ̀ sí Jesu Ìránṣẹ́ mímọ́ rẹ, ẹni tí ìwọ ti fi àmì òróró yàn,
28
láti ṣe ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ àti ìmọ̀ rẹ̀ ti pinnu ṣáájú pé yóò ṣe.
29
Ǹjẹ́ nísinsin yìí, Olúwa, kíyèsi ìhàlẹ̀ wọn; kí ó sì fi fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ láti máa fi ìgboyà ńlá sọ ọ̀rọ̀ rẹ.
30
Kí ìwọ sì fi nína ọwọ́ rẹ ṣe ìmúláradá, àti kí iṣẹ́ ìyanu máa ṣẹ̀ ní orúkọ Jesu ìránṣẹ́ mímọ́ rẹ.”
31
Nígbà tí wọ́n gbàdúrà tan, ibi tí wọ́n gbé péjọpọ̀ sí mì tìtì; gbogbo wọn sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, wọ́n sì ń fi ìgboyà sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
32
Ìjọ àwọn tí ó gbàgbọ́ sì wà ní ọkàn kan àti inú kan; kò sì ṣí ẹnìkan tí ó wí pé ohun kan nínú ohun ìní rẹ̀ jẹ́ ti ara rẹ̀; ṣùgbọ́n gbogbo wọn ní ohun gbogbo ní ìṣọ̀kan.
33
Agbára ńlá ni àwọn aposteli sì fi ń jẹ́rìí àjíǹde Jesu Olúwa, oore-ọ̀fẹ́ púpọ̀ sì wà lórí gbogbo wọn.
34
Nítorí kò sí ẹnìkan nínú wọn tí ó ṣe aláìní, nítorí iye àwọn tí ó ní ilẹ̀ tàbí ilé tà wọ́n, wọ́n sì mú owó ohun tí wọn tà wá.
35
Wọ́n sì fi í lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn aposteli, wọn sì ń pín fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe aláìní sí.
36
Àti Josẹfu, tí a ti ọwọ́ àwọn aposteli sọ àpèlé rẹ̀ ní Barnaba (ìtumọ̀ èyí tí ń jẹ ọmọ ìtùnú), ẹ̀yà Lefi, àti ará Saipurọsi.
37
Ó ní ilẹ̀ kan, ó tà á, ó mú owó rẹ̀ wá, ó sì fi í lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn aposteli.

Ọ̀rọ̀ Bíbélì: Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™, © 2009, 2017 Biblica, Inc. · CC BY-SA 4.0“Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc., used with permission.

Settings

Reading style

Typeface

Font size 19px

Reading width 75 chars

Options