2 Ọba 9:7-28
7
Kí ìwọ kí ó pa ilé Ahabu ọ̀gá à rẹ̀ run, Èmi yóò sì gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ gbogbo àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì àti gbogbo ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Olúwa tí a ta sílẹ̀ látọwọ́ ọ Jesebeli.
8
Gbogbo ilé Ahabu yóò ṣègbé. Èmi yóò gé e kúrò láti orí Ahabu gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó gbẹ̀yìn ni Israẹli, ẹrú tàbí òmìnira.
9
Èmi yóò ṣe ilé Ahabu gẹ́gẹ́ bí ilé Jeroboamu ọmọ Nebati àti ilé Baaṣa ọmọ Ahijah.
10
Fún Jesebeli, ajá ni yóò jẹ ẹ́ ní oko Jesreeli, kò sì sí ẹni tí yóò sin òkú rẹ̀.’ ” Nígbà náà ó ṣí ìlẹ̀kùn, ó sì sálọ.
11
Nígbà tí Jehu jáde lọ bá àwọn ọgbà ìjòyè e rẹ̀, ọ̀kan nínú wọn sì bi í pé, “Ṣé gbogbo nǹkan dára?” Kí ni ó dé tí aṣiwèrè fi tọ̀ ọ́ wá, “Ìwọ mọ ọkùnrin náà àti irú nǹkan tí ó ń sọ,” Jehu fèsì.
12
“Ìyẹn kì í ṣe òótọ́!” Wọ́n wí. “Sọ fún wa.” Jehu wí, “Èyí ni ohun tí ó sọ fún mi: ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí, “Èmi fi àmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Israẹli.” ’ ”
13
Wọ́n ṣe gírí, wọ́n sì mú agbádá a wọn, wọ́n sì tàn wọ́n sí abẹ́ rẹ̀ ní orí àtẹ̀gùn. Nígbà náà, wọ́n fọn ìpè, wọ́n sì kígbe, “Jehu jẹ ọba!”
14
Bẹ́ẹ̀ ni Jehu ọmọ Jehoṣafati, ọmọ Nimṣi, dìtẹ̀ sí Joramu. (Nísinsin yìí Joramu àti gbogbo Israẹli ti ń dáàbò bo Ramoti Gileadi nítorí Hasaeli ọba Aramu.
15
ṣùgbọ́n ọba Joramu ti padà sí Jesreeli láti lọ sàn nínú ọgbẹ́ tí àwọn ará Aramu ti dá sí i lára nínú ogun pẹ̀lú ọba Hasaeli ti Aramu.) Jehu wí pé, “Tí èyí bá jẹ́ ọ̀nà tí ò ń rò, má ṣe jẹ́ kí ẹnìkankan kí ó yọ jáde nínú ìlú ńlá láti lọ sọ ìròyìn náà ní Jesreeli.”
16
Nígbà náà Jehu wọ inú kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ó sì gùn ún lọ sí Jesreeli, nítorí Joramu ń sinmi níbẹ̀ àti Ahasiah ọba Juda sì sọ̀kalẹ̀ láti wá wò Joramu.
17
Nígbà tí olùṣọ́ kan tí ó dúró ní ilé ìṣọ́ ní Jesreeli, rí ọ̀wọ́ ogun Jehu tí wọ́n ń súnmọ́ tòsí, ó pè jáde, “Mo rí àwọn ọ̀wọ́ ogun tí ó ń bọ̀.” “Mú ọkùnrin ẹlẹ́ṣin kan,” Joramu pa á láṣẹ. “Rán an lọ sí ọ̀dọ̀ wọn kí o sì béèrè pé, ‘Ṣé ẹ̀yin wá pẹ̀lú àlàáfíà?’ ”
18
Ọkùnrin ẹlẹ́ṣin náà, lọ láti lọ bá Jehu ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí ọba wí: ‘Ṣé ìwọ wá pẹ̀lú àlàáfíà?’ ” “Kí ni ìwọ ní ṣe pẹ̀lú àlàáfíà?” Jehu sì dáhùn. “Bọ́ sí ẹ̀yìn mi.” Olùṣọ́ náà sì wí fún un pé, “Ìránṣẹ́ náà ti dé ọ̀dọ̀ wọn, ṣùgbọ́n kò tún padà wá mọ́.”
19
Bẹ́ẹ̀ ni, ọba rán ọkùnrin ẹlẹ́ṣin kejì. Nígbà náà ó wá sí ọ̀dọ̀ wọn, ó wí pé, “Èyí ni ohun tí ọba sọ: “Ṣé ìwọ wá pẹ̀lú àlàáfíà?” Jehu dáhùn, “Dúró sí ẹ̀yìn mi.”
20
Olùṣọ́ náà sì fi sùn. “Ó ti dé ọ̀dọ̀ wọn, ṣùgbọ́n kò tún padà wá mọ́ pẹ̀lú. Wíwá rẹ̀ sì dàbí ti Jehu ọmọ Nimṣi, ó ń wa kẹ̀kẹ́ bí ti aṣiwèrè.”
21
“Fi ìwọ̀ kọ́ kẹ̀kẹ́ ogun mi.” Joramu pa á láṣẹ. Àti nígbà tí a fi kọ́, Joramu ọba Israẹli àti Ahasiah ọba Juda, gun kẹ̀kẹ́ lọ, olúkúlùkù nínú kẹ̀kẹ́ ogun tirẹ̀, láti lọ bá Jehu. Wọ́n bá a pàdé ní ibi oko tí ó ti jẹ́ ti Naboti ará Jesreeli.
22
Nígbà tí Joramu rí Jehu, ó béèrè pé, “Ṣé ìwọ wá pẹ̀lú àlàáfíà, Jehu?” “Báwo ni àlàáfíà yóò ṣe wà,” Jehu dáhùn, “Ní ìwọ̀n ìgbà tí gbogbo ìbọ̀rìṣà àti iṣẹ́ àjẹ́ ti màmá rẹ Jesebeli di púpọ̀?”
23
Joramu yí ọwọ́ rẹ̀ padà, ó sì sálọ, ó sì ń pe Ahasiah, “Ọ̀tẹ̀ dé, Ahasiah!”
24
Nígbà náà, Jehu fa ọrun rẹ̀, ó sì yin Joramu láàrín èjìká méjèèjì. Ọfà náà sì wọ inú ọkàn rẹ̀, ó sì ṣubú lulẹ̀ láti orí kẹ̀kẹ́ rẹ̀.
25
Jehu sọ fún Bidikari, balógun kẹ̀kẹ́ ẹ rẹ̀ pé, “Gbé e sókè kí ó sì jù ú sí orí oko tí ó jẹ́ ti Naboti ará Jesreeli. Rántí bí èmi àti ìwọ ti ń gun kẹ̀kẹ́ papọ̀ lẹ́yìn Ahabu baba à rẹ nígbà tí Olúwa sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀,
26
‘Ní àná, mo rí ẹ̀jẹ̀ Naboti pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, ni Olúwa wí.’ Ǹjẹ́ nítorí náà, ẹ gbé e sókè, kí o sì jù ú sí orí ilẹ̀ oko náà ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Olúwa.”
27
Nígbà tí Ahasiah ọba, Juda rí ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀, ó sálọ sójú ọ̀nà sí Beti-Haggani. Jehu sì lépa rẹ̀, ó ń kígbe, “Pa á pẹ̀lú!” Wọ́n ṣá a ní ọgbẹ́ nínú kẹ̀kẹ́ ẹ rẹ̀ ní ọ̀nà lọ sí Guri lẹ́bàá a Ibleamu, ṣùgbọ́n ó sálọ sí Megido, ó sì kú síbẹ̀.
28
Ìránṣẹ́ rẹ̀ sì gbé e pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ lọ sí Jerusalẹmu, ó sì sin ín pẹ̀lú, baba a rẹ̀ nínú ibojì rẹ̀ ní ìlú ńlá ti Dafidi.
Settings