Skip to content
2 Kronika 4:1-14

2 Kronika 4:1-14

1
Ó ṣe pẹpẹ idẹ, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá fún gíga.
2
Ó ṣe agbada dídà ńlá tí ó rí róbótó tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá láti etí kan dé etí èkejì ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún sì ni gíga rẹ̀.
3
Lábẹ́ etí, àwòrán àwọn akọ màlúù yíká mẹ́wàá sí ìgbọ̀nwọ́ kan. Àwọn akọ màlúù náà ni á dá ní ọ̀nà méjì ní àwòrán kan pẹ̀lú okùn.
4
Okùn náà dúró lórí akọ màlúù méjìlá, mẹ́ta kọjú sí àríwá, mẹ́ta kọjú sí ìwọ̀-oòrùn, mẹ́ta kọjú sí gúúsù mẹ́ta kọjú sí ìlà-oòrùn. Òkun náà sì sinmi lórí wọn àti gbogbo ìhà ẹ̀yìn wọn sì wà ní apá àárín.
5
Ó nípọn tó ìbú àtẹ́lẹwọ́, etí rẹ̀ sì dàbí etí ife ìmumi, bí i ìtànná lílì ó sì dá ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) bati dúró.
6
Ó ṣe ọpọ́n mẹ́wàá fún fífọ nǹkan, ó sì gbé márùn-ún ka ìhà gúúsù àti márùn-ún ní àríwá. Nínú wọn ni ó ti ń fọ àwọn nǹkan tí wọ́n ń lò fún ẹbọ sísun ṣùgbọ́n, àwọn àlùfáà ní ó ń lo Òkun fún fífọ nǹkan.
7
Ó ṣe ìgbé fìtílà dúró mẹ́wàá ti wúrà gẹ́gẹ́ bí èyí tí a yàn fún wọn. A sì gbé wọn kalẹ̀ sínú ilé Olúwa márùn un ní ìhà gúúsù àti márùn-ún ní ìhà àríwá.
8
Ó ṣé tábìlì mẹ́wàá, ó sì gbé wọn sí inú ilé Olúwa, márùn un ní gúúsù àti márùn-ún ní ìhà àríwá. Ó ṣé ọgọ́rùn-ún ọpọ́n ìbùwọ́n wúrà.
9
Ó ṣe àgbàlá àwọn àlùfáà àti ààfin ńlá àti àwọn ìlẹ̀kùn fún ààfin, ó sì tẹ́ àwọn ìlẹ̀kùn náà pẹ̀lú idẹ.
10
Ó gbé Òkun náà ka orí ìhà gúúsù ní ẹ̀bá igun gúúsù àríwá.
11
Huramu ṣe àwọn ìkòkò pẹ̀lú, àti ọkọ́ àti àwọn ọpọ́n ìbùwọ́n. Bẹ́ẹ̀ ni Huramu parí iṣẹ́ tí ó ti dáwọ́lé fún ọba Solomoni ní ilé Ọlọ́run.
12
Àwọn ọ̀wọ́n méjì; ọpọ́n méjì ìparí tí ó wà lókè àwọn ọ̀wọ́n iṣẹ́; àwọn méjì ní láti bo ọpọ́n méjì ìparí tí ń bẹ lókè àwọn ọ̀wọ́n;
13
irinwó (400) pomegiranate fún iṣẹ́ ẹ̀wọ̀n méjì náà, ẹsẹ̀ méjì pomegiranate ni fún iṣẹ́ ẹ̀wọ̀n kan, láti bo ọpọ́n rìbìtì méjì náà tí ó wà lórí àwọn òpó náà;
14
ó sì ṣe àgbéró ó sì ṣe agbada sí orí wọn;
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options