Skip to content
2 Kronika 30:13-20

2 Kronika 30:13-20

13
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sì péjọ ní Jerusalẹmu, láti pa àjọ àkàrà àìwú mọ́ ní oṣù kejì.
14
Wọ́n sì dìde, wọ́n sì kó gbogbo pẹpẹ tí ó wà ní Jerusalẹmu lọ, àti gbogbo pẹpẹ tùràrí ni wọ́n kó lọ, wọ́n sì dà wọ́n sí odò Kidironi.
15
Nígbà náà ni wọ́n pa ẹran ìrékọjá náà ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kejì: ojú sì ti àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi, wọ́n sì yà ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì mú ẹbọ sísun wá sínú ilé Olúwa.
16
Wọ́n sì dúró ní ipò wọn, bí ètò wọn gẹ́gẹ́ bí òfin Mose, ènìyàn Ọlọ́run: àwọn àlùfáà wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà, tí wọ́n gbà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Lefi.
17
Nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó wà nínú ìjọ ènìyàn náà tí kò yà ara wọn sí mímọ́: nítorí náà ni àwọn ọmọ Lefi ṣe ń tọ́jú àti pa ẹran ìrékọjá fún olúkúlùkù ẹni tí ó ṣe aláìmọ́, láti yà á sí mímọ́ sí Olúwa.
18
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú Efraimu àti Manase, Isakari, àti Sebuluni kò sá wẹ̀ ara wọn mọ́ síbẹ̀ wọ́n jẹ ìrékọjá náà, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́. Ṣùgbọ́n Hesekiah bẹ̀bẹ̀ fún wọn, wí pé, Olúwa, ẹni rere, dáríjì olúkúlùkù,
19
tí ó múra ọkàn rẹ̀ láti wá Ọlọ́run, Olúwa Ọlọ́run àwọn baba rẹ̀ ṣùgbọ́n tí kì í ṣe nípa ìwẹ̀nùmọ́ mímọ́
20
Olúwa sì gbọ́ ti Hesekiah, ó sì mú àwọn ènìyàn náà láradá.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options