2 Kronika 10:6-11
6
Nígbà náà ni ọba Rehoboamu fi ọ̀ràn lọ̀ àwọn àgbàgbà tí ó ti ń sin baba rẹ̀ Solomoni nígbà ayé rẹ̀, ó sì bi wọ́n léèrè pe, “Báwo ni ẹ̀yin yóò ṣe gbà mí ní ìmọ̀ràn láti dá àwọn ènìyàn wọ̀nyí lóhùn?”
7
Wọ́n sì dáhùn, “Tí ìwọ yóò bá ṣe rere sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí kí o sì ṣe ìre fún wọn, kí o sì fún wọn ní ìdáhùn rere, wọn yóò sì máa jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ nígbà gbogbo.”
8
Ṣùgbọ́n Rehoboamu kọ ìmọ̀ràn náà tí àwọn àgbàgbà fi fún un, ó sì fi ọ̀rọ̀ lọ àwọn ọmọ ọkùnrin tí ó ti dàgbàsókè pẹ̀lú rẹ̀ tí wọ́n sì ń dúró níwájú rẹ̀.
9
Ó sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ni ìmọ̀ràn yín? Báwo ni kí a ṣe dá àwọn ènìyàn wọ̀nyí tí wọ́n wí fún mi pé, ‘Mú kí àjàgà tí baba rẹ gbé lé wa kí ó fúyẹ́ díẹ̀.’ ”
10
Àwọn ọ̀dọ́mọdé tí ó ti dàgbà pẹ̀lú rẹ dá a lóhùn pé, “Sọ fún àwọn ènìyàn tí ó wí fún ọ wí pé, ‘Baba rẹ gbé àjàgà wúwo lórí wa, ṣùgbọ́n mú àjàgà wa fúyẹ́,’ wí fún wọn pé, ‘Ìka ọwọ́ mi kékeré, ó nípọn ju ìbàdí baba mi lọ.
11
Baba mi gbé àjàgà wúwo ka orí yín; èmi yóò sì tún mú kí ó wúwo sì í. Baba mi fi pàṣán nà yín; èmi yóò sì nà yín pẹ̀lú àkéekèe.’ ”
Settings