Skip to content
1 Samuẹli 13:17-23

1 Samuẹli 13:17-23

17
Ẹgbẹ́ àwọn onísùmọ̀mí mẹ́ta jáde lọ ní àgọ́ àwọn Filistini ní ọnà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ẹgbẹ́ kan gba ọ̀nà ti Ofira ní agbègbè ìlú Ṣuali,
18
òmíràn gba ọ̀nà Beti-Horoni, ẹ̀kẹta sí ìhà ibodè tí ó kọjú sí àfonífojì Seboimu tí ó kọjú sí ijù.
19
A kò sì rí alágbẹ̀dẹ kan ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli, nítorí tí àwọn Filistini wí pé, “Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ àwọn Heberu yóò rọ idà tàbí ọ̀kọ̀!”
20
Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Israẹli tọ àwọn Filistini lọ láti pọ́n dòjé wọn, ọ̀kọ̀, àáké àti ọ̀ṣọ́ wọn.
21
Iye tí wọ́n fi pọ́n dòjé àti ọ̀kọ̀ jẹ́ ọwọ́ méjì nínú ìdámẹ́ta ṣékélì, àti ìdámẹ́ta ṣékélì fún pípọ́n òòyà-irin tí ilẹ̀, àáké àti irin ọ̀pá olùṣọ́ màlúù.
22
Bẹ́ẹ̀ ni ọjọ́ ìjà ẹnìkankan nínú àwọn ọmọ-ogun tí ó wà pẹ̀lú Saulu àti Jonatani kò sì ní idà, tàbí ọ̀kọ̀ ní ọwọ́; àfi Saulu àti ọmọ rẹ̀ Jonatani ni wọ́n ni wọ́n.
23
Àwọn ẹgbẹ́ ogun Filistini sì ti jáde lọ sí ìkọjá Mikmasi.
Settings

Reading style

Typeface

Font size 19px

Reading width 75 chars

Options