Ìmọ̀ràn Nípa Àwọn Wúńdíá àti Ìpọ́njú Àkókò Yìí
25
Ṣùgbọ́n nípa ti àwọn wúńdíá, èmi kò ní àṣẹ kankan láti ọ̀dọ̀ Olúwa, ṣùgbọ́n mo wí fún yín ní ìdájọ́ bí ẹni tí ó rí àánú Olúwa gbà láti jẹ́ olódodo.
26
Nítorí náà mo rò pé èyí dára nítorí wàhálà ìsinsin yìí, èyí nì ni pé o dára fún ènìyàn kí ó wà bí o ṣe wà.
27
Ǹjẹ́ ó ti ṣe ẹlẹ́rìí láti fẹ́ ìyàwó. Ẹ má ṣe kọ ara yín sílẹ̀, nítorí èyí tí mo wí yìí. Ṣùgbọ́n tí o kò bá sì tí ìgbéyàwó, tàbí fẹ́ ọkọ, má ṣe sáré láti ṣe bẹ́ẹ̀ lákokò yìí.
28
Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá gbé ìyàwó ìwọ kò dẹ́ṣẹ̀, bí a bá gbé wúńdíá ní ìyàwó òun kò dẹ́ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n irú àwọn tí ó bá gbé ìyàwó yóò dojúkọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà nípa ti ara, ṣùgbọ́n èmi fẹ́ dá a yín sí.
29
Òun ti mo ń wí ará, ni pé kúkúrú ni àkókò, láti ìsinsin yìí lọ, ẹni tí ó ni aya kí ó dàbí ẹni tí kò ní rí;
30
àwọn tí ń sọkún, bí ẹni pé wọn kò sọkún rí, àti àwọn tí ń yọ̀ bí ẹni pé wọn kò yọ̀ rí, àti àwọn tí ń rà bí ẹni pé wọn kò ní rí,
31
àti àwọn tó ń lo ohun ayé yìí, bí ẹni tí kò ṣe àṣejù nínú wọn: nítorí ìgbà ayé yìí ń kọjá lọ.
32
Nínú gbogbo nǹkan tí ẹ bá ń ṣe ni mo tí fẹ́ kí ẹ sọ ara yín di òmìnira lọ́wọ́ àníyàn. Ọkùnrin tí kò ní ìyàwó le lo àkókò rẹ̀ láti fi ṣiṣẹ́ fún Olúwa, yóò sì má ronú bí ó ti ṣe le tẹ́ Olúwa lọ́rùn.
33
Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí ó bá tí ṣe ìgbéyàwó kò le ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí ó ní láti ronú àwọn nǹkan rẹ̀ nínú ayé yìí àti bí ó ti ṣe le tẹ́ aya rẹ̀ lọ́rùn,
34
dájúdájú, ìfẹ́ rẹ̀ pín sí ọ̀nà méjì. Bákan náà ló rí fún obìnrin tí a gbé ní ìyàwó àti wúńdíá. Obìnrin tí kò bá tí ì délé ọkọ a máa tọ́jú ohun tí ṣe ti Olúwa, kí òun lè jẹ́ mímọ́ ní ara àti ní ẹ̀mí. Ṣùgbọ́n ọmọbìnrin tí a bá ti gbé níyàwó, a máa ṣe ìtọ́jú ohun tí ṣe ti ayé, bí yóò ti ṣe le tẹ́ ọkọ rẹ̀ lọ́rùn.
35
Mo ń sọ èyí fún àǹfààní ara yín kì í ṣe láti dá yín lẹ́kun ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè gbé ní ọ̀nà tí ó tọ́ kí ẹ sì lè máa sin Olúwa láìsí ìyapa ọkàn.
Settings