1 Kọrinti 7:17-24
17
Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí olúkúlùkù máa gbé ìgbé ayé tí Ọlọ́run ń fẹ́ yín fún, àti nínú èyí tí Olúwa pè é sí. Ìlànà àti òfin mi fún gbogbo ìjọ ni èyí.
18
Ǹjẹ́ ọkùnrin kan ha ti kọlà nígbà tí a pè é? Kí ó má sì ṣe di aláìkọlà. Ǹjẹ́ ọkùnrin kan ha ti kọlà nígbà tí a pè é? Kí ó ma ṣe kọlà.
19
Ìkọlà kò jẹ́ nǹkan àti àìkọlà kò jẹ́ nǹkan, bí kò ṣe pípa òfin Ọlọ́run mọ́.
20
Ó yẹ kí ẹnìkọ̀ọ̀kan máa ṣe iṣẹ́ tí ó ń ṣe tẹ́lẹ̀, kí Ọlọ́run tó pé é sínú ìgbàgbọ́ nínú Kristi.
21
Ǹjẹ́ ẹrú ni ọ́ bí nígbà ti a pè ọ́? Má ṣe kà á sí. Ṣùgbọ́n tí ìwọ bá le di òmìnira, kúkú ṣe èyí nì.
22
Tí ó bá jẹ́ ẹrú, ti Olúwa sì pé ọ, rántí pé Kristi ti sọ ọ́ di òmìnira kúrò lọ́wọ́ agbára búburú ti ẹ̀ṣẹ̀. Tí ó bá sì ti pé ọ̀ nítòótọ́ tí ó sì ti di òmìnira, ó ti di ẹrú Kristi.
23
A sì ti rà yín ní iye kan, nítorí náà ẹ má ṣe di ẹrú ènìyàn.
24
Ará, jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn, nínú èyí tí a pè é, kí ó dúró nínú ọ̀kan náà pẹ̀lú Ọlọ́run.
Settings