Skip to content
1 Kọrinti 14:1-16

1 Kọrinti 14:1-16

1
Ẹ máa lépa ìfẹ́, ki ẹ sí máa fi ìtara ṣàfẹ́rí ẹ̀bùn tí í ṣe ti Ẹ̀mí, ṣùgbọ́n ki ẹ kúkú lé máa sọtẹ́lẹ̀.
2
Nítorí ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ní èdè àìmọ̀, kò bá ènìyàn sọ̀rọ̀ bì ko ṣe Ọlọ́run: nítorí kó sí ẹni tí ó gbọ́; ṣùgbọ́n nípá ti Ẹ̀mí ó ń sọ ohun ìjìnlẹ̀.
3
Ṣùgbọ́n ẹni tí ń sọtẹ́lẹ̀ ń ba àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ fún ìmúdúró, àti ìgbaniníyànjú, àti ìtùnú.
4
Ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ni èdè àìmọ̀ ń fi ẹsẹ̀ ara rẹ̀ mulẹ̀; ṣùgbọ́n ẹni ti ń sọtẹ́lẹ̀ ń fi ẹsẹ̀ ìjọ múlẹ̀.
5
Ṣùgbọ́n ìbá wù mí ki gbogbo yín lè máa sọ onírúurú èdè, ṣùgbọ́n kí ẹ kúkú máa sọtẹ́lẹ̀, ẹni tí ń sọtẹ́lẹ̀ pọ̀ jú ẹni ti ń fèdèfọ̀ lọ, bi kọ ṣe pé ó bá ń ṣe ìtumọ̀, kí ìjọ bá à lè kọ́ ẹ̀kọ́.
6
Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ará, bí mo bá wá sí àárín yín, tí mo sì ń sọ̀rọ̀ ní èdè àìmọ̀, èrè kín ni èmi yóò jẹ́ fún yin, bi ko ṣe pé mo bá ń bá yín sọ̀rọ̀, yálà nípa ìṣípayá, tàbí ìmọ̀ tàbí nípá ìsọtẹ́lẹ̀, tàbí nípa ẹ̀kọ́?
7
Bẹ́ẹ̀ ní pẹ̀lú àwọn nǹkan tí kò ní ẹ̀mí tí ń dún, ìbá à ṣe fèrè tàbí dùùrù bí kò ṣe pé ìyàtọ̀ bá wà nínú wọn, a ó tí ṣe mọ ohùn tí fèrè tàbí tí dùùrù ń wí?
8
Nítorí pé bi ohùn ìpè kò bá dájú, ta ni yóò múra fún ogun?
9
Bẹ́ẹ̀ sí ni ẹ̀yin, bí kò ṣe pé ẹ̀yin bá ń fi ahọ́n yín sọ̀rọ̀ tí ó yé ni, a ó ti ṣe mọ ohun ti ẹ ń wí? Nítorí pé ẹ̀yin yóò kàn máa sọ̀rọ̀ si afẹ́fẹ́ lásán.
10
Ó lé jẹ́ pé onírúurú ohùn èdè ní ń bẹ ní ayé, kò sí ọ̀kan tí kò ní ìtumọ̀.
11
Ǹjẹ́ bí èmí kò mọ ìtumọ̀ ohùn èdè náà, èmí ó jásí aláìgbédè sí ẹni tí ń sọ̀rọ̀, ẹni tí ń sọ̀rọ̀ yóò sí jásí aláìgbédè sí mi.
12
Bẹ́ẹ̀ sì ní ẹ̀yin, bí ẹ̀yin ti ní ìtara fún ẹ̀bùn Ẹ̀mí, ẹ máa ṣe àfẹ́rí àti máa pọ̀ sí i fún ìdàgbàsókè ìjọ.
13
Nítorí náà jẹ́ ki ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ni èdè àìmọ̀ gbàdúrà ki ó lè máa ṣe ìtumọ̀ ohun tí ó sọ.
14
Nítorí bí èmi bá ń gbàdúrà ní èdè àìmọ̀, ẹ̀mí mi ni ń gbàdúrà, ṣùgbọ́n ọkàn mi jẹ́ aláìléso.
15
Ǹjẹ́ kín ni èmi yóò ṣe? Èmi yóò fi ẹ̀mí mi gbàdúrà, èmi yóò sí fi òye mi gbàdúrà pẹ̀lú; Èmi yóò fi ẹ̀mí mi kọrin, èmi yóò sí fi òye mi kọrin pẹ̀lú.
16
Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, bí ìwọ bá yin Ọlọ́run nípa ẹ̀mí, báwo ni ẹni tí ń bẹ ni ipò òpè yóò ṣe ṣe “Àmín” si ìdúpẹ́ rẹ, nígbà tí kò mọ ohun tí ìwọ wí?
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options