Skip to content
1 Kọrinti 12:22-31

1 Kọrinti 12:22-31

22
Àwọn ẹ̀yà ara tí ó dàbí ẹni pé wọ́n ṣe aláìlágbára jùlọ, tí ó dàbí ẹni pé kò ṣe pàtàkì rárá, àwọn gan an ni a kò le ṣe aláìnílò.
23
Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yà ara tí a rò pé kò lọ́lá rárá ni àwa ń fi ọlá fún jùlọ. Àwọn ẹ̀yà ara tí a rò pé ko yẹ rárá ni àwa ń fi si ipò ọlá ẹ̀yẹ tí ó ga jùlọ.
24
Nítorí pé àwọn ibi tí ó ní ẹ̀yẹ ní ara wa kò nílò ìtọ́jú ọ̀tọ̀. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti pa gbogbo ẹ̀yà ara pọ̀ ṣọ̀kan lọ́nà kan, ó sì ti fi ẹ̀yẹ tó ga jùlọ fún ibi tí ó ṣe aláìní.
25
Kí ó má ṣe sí ìyàtọ̀ nínú ara, ṣùgbọ́n kí àwọn ẹ̀yà ara le máa jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún ara wọn.
26
Bí ẹ̀yà ara kan bá ń jìyà, gbogbo àwọn ẹ̀yà ara ìyókù a máa bá a pín nínú ìyà náà. Tí a bá sì bu ọlá fún ẹ̀yà ara kan, gbogbo ẹ̀yà ara ìyókù a máa bá a yọ̀.
27
Gbogbo yín jẹ́ ara Kristi, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín sì jẹ́ ẹ̀yà ara ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú ara Kristi.
28
Ọlọ́run sì gbé àwọn mìíràn kalẹ̀ nínú ìjọ, èkínní àwọn aposteli, èkejì àwọn wòlíì, ẹ̀kẹta àwọn olùkọ́ni, lẹ́yìn náà, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìyanu, lẹ́yìn náà àwọn tí ó ní ẹ̀bùn ìmúláradá, àwọn olùrànlọ́wọ́ àti àwọn agbani nímọ̀ràn, àwọn tí ń sọ onírúurú èdè.
29
Ǹjẹ́ gbogbo ènìyàn ni ó jẹ́ aposteli bi? Tàbí gbogbo ènìyàn ni wòlíì bí? Ṣe gbogbo ènìyàn ní olùkọ́ni? Ṣé gbogbo ènìyàn ló ní agbára láti ṣe iṣẹ́ ìyanu bí?
30
Ṣé gbogbo ènìyàn ló lè wonisàn bí? Rárá. Ǹjẹ́ gbogbo wa ni Ọlọ́run fún ní ẹ̀bùn láti le sọ̀rọ̀ ní èdè tí a kò ì tí ì gbọ́ rí bí? Ṣé ẹnikẹ́ni ló lè túmọ̀ èdè tí wọ́n sọ tí kò sì yé àwọn ènìyàn bí?
31
Ṣùgbọ́n, ẹ máa fi ìtara ṣàfẹ́rí ẹ̀bùn ti ó tóbi jù. Síbẹ̀ èmi o fi ọ̀nà kan tí ó tayọ rékọjá hàn yín.
Settings

Reading style

Typeface

Font size 19px

Reading width 75 chars

Options