1 Kronika 2:42-55
42
Àwọn ọmọ Kalebu arákùnrin Jerahmeeli: Meṣa àkọ́bí rẹ̀, ẹni tí ó jẹ́ baba fún Sifi, àti àwọn ọmọ rẹ̀ Meraṣa, ẹni tí ó jẹ́ baba fún Hebroni.
43
Àwọn ọmọ Hebroni: Kora, Tapua, Rekemu, àti Ṣema.
44
Ṣema ni baba Rahamu, Rahamu sì jẹ́ baba fún Jorkeamu. Rekemu sì ni baba Ṣammai.
45
Àwọn ọmọ Ṣammai ni Maoni, Maoni sì ni baba Beti-Suri.
46
Efani obìnrin Kalebu sì ni ìyá Harani, Mosa àti Gasesi, Harani sì ni baba Gasesi.
47
Àwọn ọmọ Jahdai: Regemu, Jotamu, Geṣani, Peleti, Efani àti Ṣaafu.
48
Maaka obìnrin Kalebu sì ni ìyá Seberi àti Tirhana.
49
Ó sì bí Ṣaafu baba Madmana, Ṣefa baba Makbena àti baba Gibeah, ọmọbìnrin Kalebu sì ni Aksa.
50
Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Kalebu. Àwọn ọmọ Huri, àkọ́bí Efrata: Ṣobali baba Kiriati-Jearimu.
51
Salma baba Bẹtilẹhẹmu àti Harefu baba Beti-Gaderi.
52
Àwọn ọmọ Ṣobali baba Kiriati-Jearimu ni: Haroe, ìdajì àwọn ará Manaheti.
53
Àti ìdílé Kiriati-Jearimu: àti àwọn ara Itri, àti àwọn ará Puti, àti àwọn ará Ṣumati àti àwọn ará Miṣraiti: láti ọ̀dọ̀ wọn ni àwọn ọmọ ará Sorati àti àwọn ará Eṣtaoli ti wá.
54
Àwọn ọmọ Salma: Bẹtilẹhẹmu, àti àwọn ará Netofa, Atrotu Beti-Joabu, ìdajì àwọn ará Manahati, àti ará Sori,
55
àti àwọn ìdílé àwọn akọ̀wé, ẹni tí ń gbé ní Jabesi: àti àwọn ọmọ Tirati àti àwọn ará Ṣimeati àti àwọn ará Sukati. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ará Keni, ẹni tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Hamati, baba ilé Rekabu.
Settings