Skip to content
1 Kronika 19:1-7

1 Kronika 19:1-7

1
Ní àkókò yí, Nahaṣi ọba àwọn ará Ammoni sì kú, ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.
2
Dafidi rò wí pé èmi yóò fi inú rere hàn sí Hanuni ọmọ Nahaṣi, nítorí baba a rẹ̀ fi inú rere hàn sí mi. Bẹ́ẹ̀ ni, Dafidi rán àwọn aṣojú lọ láti lọ fi ìbá kẹ́dùn rẹ̀ hàn sí Hanuni ní ti baba a rẹ̀. Nígbà tí àwọn ọkùnrin Dafidi wá sí ọ̀dọ̀ Hanuni ní ilẹ̀ àwọn ará Ammoni láti fi ìbá kẹ́dùn rẹ̀ hàn sí i.
3
Àwọn ọkùnrin ọlọ́lá ti Ammoni sọ fún Hanuni pé, “Ṣé ìwọ rò pé Dafidi ń bu ọlá fún baba rẹ nípa rírán àwọn olùtùnú sí ọ? Ṣé àwọn ọkùnrin rẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ láti rìn wò àti láti bì í ṣubú, àti láti ṣe ayọ́lẹ̀wò ilẹ̀ náà.”
4
Bẹ́ẹ̀ ni Hanuni fi ipá mú àwọn ọkùnrin Dafidi, fá irun wọn, wọ́n gé ẹ̀wù wọn kúrò ní àárín ìdí rẹ̀, ó sì rán wọn lọ.
5
Nígbà tí ẹnìkan wá, tí ó sì sọ fún Dafidi nípa àwọn ọkùnrin rẹ̀, ó rán àwọn ìránṣẹ́ láti lọ bá wọn, nítorí wọ́n ti di rírẹ̀ sílẹ̀ gidigidi. Ọba wí pe, “Dúró ní Jeriko títí tí irùngbọ̀n yín yóò fi hù, nígbà náà ẹ padà wá”.
6
Nígbà tí àwọn ará Ammoni sì ri pé wọ́n ti di ẹ̀ṣẹ̀ ní ihò imú Dafidi, Hanuni àti àwọn ará Ammoni rán ẹgbẹ̀rún (1,000) tálẹ́ǹtì fàdákà láti gba iṣẹ́ àwọn kẹ̀kẹ́ àti àwọn agun-kẹ̀kẹ́ láti Aramu-Naharaimu, Siria Maaka àti Soba.
7
Wọ́n gba iṣẹ́ ẹgbẹ̀rin méjìlélọ́gbọ̀n (32,000) kẹ̀kẹ́ àti agun-kẹ̀kẹ́ àti ọba Maaka pẹ̀lú àwọn ọ̀wọ́ ọmọ-ogun rẹ̀ tí ó wá pàgọ́ ní ẹ̀bá Medeba, nígbà tí àwọn ará Ammoni kójọpọ̀ láti ìlú wọn, tí wọ́n sì jáde lọ fún ogun.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options