Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Worship: Loved by His people

6 ẹsẹ · 14 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Loved by His people

  1. Ohun kan ni mo béèrè lọ́dọ̀ Olúwa, òhun ni èmi yóò máa wá kiri: kí èmi kí ó le wà ní ilé Olúwa ní ọjọ́ ayé mi gbogbo, kí èmi: kí ó le kíyèsi ẹwà Olúwa, kí èmi kí ó sì máa wà ní tẹmpili rẹ̀.

  2. Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu. Ibùgbé rẹ̀ ti lẹ́wà tó, Olúwa àwọn ọmọ-ogun!

  3. Ọkàn mi ń ṣàfẹ́rí nítòótọ́ ó tilẹ̀ pòǹgbẹ fún àgbàlá Olúwa àyà mi àti ara mi ń kọrin ayọ̀ sí Ọlọ́run alààyè.

  4. Nítòótọ́ ológoṣẹ́ ri ilé, ẹyẹ alápáǹdẹ̀dẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ fún ara rẹ̀, níbi tí yóò máa pa ọmọ rẹ̀ mọ́ sí: ibùgbé ní tòsí pẹpẹ rẹ̀, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ọba mí àti Ọlọ́run mi.

  5. Dídára ní ọjọ́ kan ní ààfin rẹ ju ẹgbẹ̀rún (1,000) ọjọ́ lọ; èmi o kúkú máa ṣe aṣọ́nà nínú ilé Ọlọ́run mi jù láti gbé ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú.

  6. Àwọn ẹni tí ń gbé ìlú ńlá kan yóò lọ sí òmíràn, wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a yára lọ gbàdúrà kí a sì wá ojúrere Olúwa, àti láti wá Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Èmi pẹ̀lú yóò sì lọ.’