Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Wine Press

8 ẹsẹ · 3 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. A ó ka ọrẹ rẹ gẹ́gẹ́ bí ọkà irúgbìn láti ilẹ̀ ìpakà tàbí wáìnì láti fún wa.

  2. “Sọ fún àwọn ọmọ pé, ‘Nígbà tí ẹ̀yin bá mú ìpín tí ó dára jù wá, a ó kà á sí fún àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí ìkórè láti ilẹ̀ ìpakà tàbí ìfúntí yín.

  3. Fi tọkàntọkàn fún un láti inú agbo ewúrẹ́ rẹ, ilẹ̀ ìpakà rẹ, àti ibi ìfúntí rẹ. Fún un gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti bùkún fún ọ tó.

  4. Ní ọjọ́ kan angẹli Olúwa wá, ó sì jókòó ní abẹ́ igi óákù Ofira èyí ti ṣe ti Joaṣi ará Abieseri, níbi tí Gideoni ọmọ rẹ̀ ti ń lu ọkà jéró, níbi ìpọntí wáìnì láti fi pamọ́ kúrò níwájú àwọn ará Midiani.

  5. Ó tu ilẹ̀ rẹ̀, ó ṣa òkúta ibẹ̀ kúrò ó sì gbin àyànfẹ́ àjàrà sí i. Ó kọ́ ilé ìṣọ́ sí inú rẹ̀ ó sì ṣe ìfúntí kan síbẹ̀ pẹ̀lú. Lẹ́yìn náà, ó ń retí èso àjàrà dáradára, ṣùgbọ́n èso búburú ni ó ti ibẹ̀ wá.

  6. Ayọ̀ àti ìdùnnú ti kúrò nínú ọgbà àjàrà àti oko Moabu. Mo dá ọwọ́ ṣíṣàn ọtí wáìnì dúró lọ́dọ̀ olùfúntí; kò sí ẹni tí ó ń tẹ̀ wọ́n pẹ̀lú igbe ayọ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igbe wà, wọn kì í ṣe igbe ti ayọ̀.

  7. “Ẹ gbọ́ òwe mìíràn, Baálé ilé kan tí ó gbin ọgbà àjàrà, ó ṣe ọgbà yìí ká, ó wá ibi ìfúntí sínú rẹ̀, ó kọ́ ilé ìṣọ́. Ó sì fi oko náà ṣe àgbàtọ́jú fún àwọn àgbẹ̀ kan, ó sì lọ sí ìrìnàjò.

  8. Lẹ́yìn ìgbà tí Jesu pa àwọn olórí ẹ̀sìn lẹ́nu mọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ pé, “Ọkùnrin kan gbin ọgbà àjàrà kan. Ó ṣe ọgbà yìí ká, ó sì wá ibi ìfúntí wáìnì, ó sì kọ́ ilé ìṣọ́ sí i ó sì fi ṣe àgbàtọ́jú fún àwọn olùṣọ́gbà, ó sì lọ sí ìrìnàjò tí ó jìnnà.